Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà àná, Abíọ́lá Ajimọbi, kìí ṣe ẹni tó lè yọ́ só
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 6, 2020

Gómìnà àná, Abíọ́lá Ajimọbi, kìí ṣe ẹni tó lè yọ́ só

Gómìnà àná, Abíọ́lá Ajimọbi, kìí ṣe ẹni tó lè yọ́ só

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àdúrà kí ẹbí ẹni dàgbà dògbò nínú àlàáfíà àti ara pípé ni kóówá máa ń gbà. Kò sí ọmolúàbí tí í gbàdúrà kí èèyàn rẹ̀ dùbúlẹ̀ àìsàn.

Ní ààrin ọ̀sẹ̀ yìí ni ìròyìn kan jáde sí ìgboro ayé pé lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn ni gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ọ̀hún wà ní iléèwòsàn ńlá kan nílùú Èkó.

Ìròyìn náà tilẹ̀ fi kún un pé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n gbé Sẹ́nétọ̀ Ajímọ̀bi dìgbàdìgbà lọ síléèwòsàn tí à ń ṣọ̀rọ̀ rẹ̀ ọ̀hún nígbà tí ọ̀rọ̀ ìlera rẹ̀ ń ṣebí ẹni fẹ́ máa mẹ́hẹ eléyìí tó sì ń dá àyà já àwọn mọ̀lẹ́bí àgbà òsèlú náà..

Wọ́n ní jíjí tí Olóyè Ajimọbi jí lọ́jọ́ náà láti ṣ’ẹ́mi ára tó sì padà sí inú yàrá rẹ ló bá ṣubúlulẹ̀ dákú rangbọndan kí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ tó gbé e dìgbàdìgbà lọ sí iléèwòsàn.

À mọ́ ṣá, nínú ìlépa àti mọ̀ bóyá lóòtọ́ ni ìròyìn yìí tàbí irọ́, ni akọròyìn ti fi ìpè ṣọwọ́ sí ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó sún mọ́ ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà láti mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ náà

Ohun tí onít’ọ̀hún tí kò fẹ́ kí orúkọ rẹ̀ hànde ṣe lálàyé ni pé, kò sí òótọ́ kan nínú Ìròyìn náà àti pé ṣáká lara baba le.

Fídíò kan tó fi síta lójú òpó Sítágíràmù rẹ lọ́jọ́ kínní, oṣù karùn ún ni Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi ti ń kí Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera àti ààbò fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń gbé ṣe lórí ìgbésẹ̀ àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn Kofi -19 l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Bákan náà ló farahàn níbi ètò ìdánilẹ́kọ́ọ̀ orí afẹ́fẹ́ kan eléyìí tí iléeṣẹ́ rédíò kan ṣe lásìkò ààwẹ̀ Ramadan tó wáyé lósù karùn ún níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bí Alága ètò ìdánilẹ́kọ́ọ̀ ààwẹ̀ náà

Pẹ̀lú ìròyìn tó ń jà rànyìnrànyìn nílẹ̀ yìí àti ohun tí ẹni tó súnmọ́ Sẹ́nétọ̀ Ajímọ̀bi sọ yìí, ìbéèrè tó wá gbòde lẹ́nu àwọn olólùfẹ́ àgbà òṣèlú yìí àtàwọn òǹwòye ni pé,
‘Níbo gan an ni Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi wà lọ́wọ́ yìí?
Ìròyìn Òwúrọ̀ gbàá ládùúrà pé, kí àlèékún àlàáfíà ó máa jẹ́ fún baba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…