Home ÀKỌ̀TUN Ó ṣèjọba Òǹdó ijọ́un f’ọ́dun kan at’oṣù mẹ́wàá–Bámidélé Olúmilúà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 5, 2020

Ó ṣèjọba Òǹdó ijọ́un f’ọ́dun kan at’oṣù mẹ́wàá–Bámidélé Olúmilúà

Ó ṣèjọba Òǹdó ijọ́un f’ọ́dun kan at’oṣù mẹ́wàá–Bámidélé Olúmilúà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ikú pabírí, ikú pàlàárì baba ẹ̀wù, ikú pa sányán baba aṣọ. Kò sèèyan tó ko baba rẹ kò níí dìgbòòrò.
Yorùbá ní ọjọ́ táa délé ayé kò tó ọjọ́ tá a bá kú, nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wa ni yóó sọ nípa ohun tá a gbé ilé ayé ṣe.

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí fún gómìnà tẹ́lẹ̀ nípìńlẹ̀ Òǹdó ijọ́un, tíí tún ṣe àgbà òsèlú àti májẹ̀óbàjẹ́ ìlú, Bámidélé Ìṣọ̀lá Olúmilúà tó jáde láyé ní àárọ̀ Ọjọ́rú.

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé aríse ni aríkà, aríkà ni baba ìrègún, ohun tá a bá fi òní ṣe, ìtàn ni yóó dà lọ́jọ́ ọ̀la, ìdí tí ìtàn fi ń fọhùn lẹ́yìn Bámidélé Ìṣọ̀lá Olúmilúà àgbà òsèlú tó gbékuru gàjà.

Ọdún 1940 ni wọ́n bí Bamidele sílù ú Ìkẹ́rẹ́ Èkìtì, ó kàwé, ó gboyè rẹpẹtẹ ní Nàìjíríà àti lókè òkun, kó tó darapọ̀ mọ́ ètò òsèlú.

Bamidele darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú Ẹlẹ́ṣin SDP ní sáà ìṣèjọba alágbádá kẹta, tó sì dupò wọlé gómìnà nípìńlẹ̀ Òǹdó ijọ́un ní oṣù Kínní ọdún 1992.

Lásìkò tí Olúmilúà jẹ́ gómìnà, Olusegun Agagu ni Igbákejì rẹ̀, nígbà tí Dókítà Olusegun Mimiko jẹ́ Kọmísánà fétò ìlera, ohun ìwúrí ló jẹ́ pé Agagu àti Mimiko padà jẹ gómìnà nípìńlẹ̀ Òǹdó, lẹ́yìn Olúmilúà.

Àmọ́ kòkòrò àwọn ológun kò jẹ́ kí àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Òǹdó gbádùn obì Olúmilúà tó gbó káká, nítorí oṣù Kọkànlá ọdún 1993 ni àwọn ológun gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú alágbádá, èyí tí olóògbé Sani Abacha ṣe agbétẹrù rẹ̀, tí wọ́n sì yẹ àga àkóso mọ́ Olúmilúà nídìí.

Yorùbá ní bí ẹṣin bá dá ni, à á tún un gùn, ìdí rèé tí Bámidélé tún fi dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP lọ́dún 1998, tí wọ́n sì yàn án sípò Alága ìgbìmọ̀ tó ń sètò ìdẹ̀rùn fáwọn arìnrìnàjò sílẹ̀ mímọ́ Jérúsálẹ́ẹ̀mù

Àmọ́ nínú oṣù kẹjọ ọdún 2005, ni ẹgbẹ́ òsèlú PDP fi ìkéde síta pé Bámidélé Olúmilúà kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ òun mọ́, nígbà tó sì di ọdún 2006 ni olóògbé náà darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìlú kan láti dá ẹgbẹ́ òsèlú Action Congress, AC sílẹ̀.

Ní ọdún 2012 tún ni wọ́n yan Olúmilúà gẹ́gẹ́ bíi baba ìsàlẹ̀ Fásitì ìpínlẹ̀ Èkìtì, EKSU.

Nígba tó jẹ́ pé àwáyé kú kò sí, Bámidélé Olúmilúà jẹ́ ìpè Ọlọ́run ní òwúrọ̀ kùtù hàì Ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹrin oṣù Kẹfà ọdún 2020 lẹ́ni ọgọ́rin ọdún nílù ú rẹ̀, Ìkẹ́rẹ́ Èkìtì.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…