Home ÀKỌ̀TUN Eyín ọ̀ọ́kán mi ni Barakat tí wọ́n fikúgbóná pa- Ìyá Barakat
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 4, 2020

Eyín ọ̀ọ́kán mi ni Barakat tí wọ́n fikúgbóná pa- Ìyá Barakat

Eyín ọ̀ọ́kán mi ni Barakat tí wọ́n fikúgbóná pa- Ìyá Barakat

Fẹ́mi Akínṣọlá

Huùnhún! Ọmọ layọ̀lé , ẹni ọmọ sin ló bímọ.
Àdúrà kí abiamọ má fojú sunkú ní gbogbo ìdílé máa ń gbà, kí iṣu ọmọ le jinná fúnni jẹ.

A mọ́ kín ni ká ti pé ti ìdílé yìí tí ẹbí àti àwọn aládùgbóò péjú p’ésẹ̀ sí lé e wọn , lati kẹ́dùn arábìnrin Barakat Bello, ọmọ ọdún méjìdínlógún tí àwọn oníṣẹ́ ibi kan gba ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fi ipá báa lò pọ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Lẹ́yìn tí Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí àwọn Ilé ẹ̀kọ́ di títì pa ni Barakat kúrò nínú ọgbà Ilé ẹ̀kọ́ tí a ti ń kọ́ nípa ìlera ohun ọ̀sìn àti ohun ọ̀gbìn, “Federal College of Animal Health and Production”, ní agbègbè Àpáta nílù Ìbàdàn, gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ onípele kínní .

Àdúgbò Oloro ní agbègbè Akinyẹle nílù ú Ìbàdàn ni Barakat ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ láti ìgbà náà.

Ìyá olóògbé Barakat, arábìnrin Kafayat Bello bá akọròyìn ṣọ̀rọ̀ pé Kafayat ní Barakat àti àbúrò rẹ̀ ọmọkùnrin ẹni ọdún bíi méje sí mẹ́jọ ni wọ́n fi sílé ní ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.

Wọ́n ní lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ ni àbúrò tí ó jẹ́ ọkùnrin jáde lọ ra nǹkan tí ó sì ku olóògbé nìkan sílé.

Ìgbà tí àbúrò tó jáde lọ yóó fi padà sílé ni ó dédé kan ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ní ìtòsí balùwẹ̀ wọn tó ń bẹ ní ẹ̀yìnkùlé.

Ariwo ọmọkùnrin náà ló jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo aládùgbóò pé ọ̀fọ̀ ti ṣẹ̀.

Bí a ṣe gbọ́,ike omi méjì tí olóògbé pọn láti fi wẹ̀ ṣì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ balùwẹ̀ náà títí pẹ̀lú àmì àgbàrá ẹ̀jẹ̀ olóògbé.

Lẹ́yìn ò rẹyìn ni wọ́n késí fi ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì náà tó ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá létí, tí àyẹ̀wò ìṣègùn ṣì fihàn nípa ikú gbígbóná tí olóògbé kú, lẹ́yìn tí wọ́n fi ipá báa lò pọ̀ tán.

Ìyá Barakat ṣàpèjúwe ọmọ rẹ̀ tí wọ́n fikú gbígbóná gbẹ́mì rẹ̀ yìí, gẹ́gẹ́ bíi eyín ọ̀ọ́kán àti ògo ìdílé tí òun àti bàbá rẹ̀ ń retí pé yóó tọ́jú àwọn àti àbúrò rẹ̀ títí dọjọ́ ogbó .

Ó ní òun bẹ Ọlọ́run kí Ó tú àṣírí àwọn afòòkùn sìkà ẹ̀dá náà lati tí ó hùwà ibi yìí kí ó tó di ọjọ́ méje.

Ẹ̀gbọ́n ìyá olóògbé náà tí ó bá akọròyìn ṣọ̀rọ̀, Arákùnrin Ọlalẹyẹ Dauda ní Barakat nìkan ló le sàlàyé bí ẹmi ṣe bọ́ lọ́rùn òun.

Dauda sọ pé,ọgbẹ́ ọkàn ńlá gbáà ni ikú ọmọbìnrin náà dá sílẹ̀ torí pé ó jẹ́ ọmọ dáadáa tí àwọn èèyàn fẹ́ràn nígbà ayé rẹ̀.

Lọ́jọ́ tí Barakat kú náà ni wọ́n ṣìnkún rẹ̀ ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí.

Lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyìí, àjọ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí lórí àwọn olubi ẹ̀dá tó dá ìdílé náà loro, fi igi ṣóńṣó bọ ojú egbò oníjàkùtẹ̀ wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …