Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ẹni tó fẹ́ ba Queen Waka lórúkọjẹ́ lọ́jọ́sí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 2, 2020

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ẹni tó fẹ́ ba Queen Waka lórúkọjẹ́ lọ́jọ́sí

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ẹni tó fẹ́ ba Queen Waka lórúkọjẹ́ lọ́jọ́sí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ kàwé kẹ́kọ́ọ̀ gboyè kò pé kò má gọ̀, bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rọ̀ rí fún ọmọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndinlógún kan tó tún jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè National Diploma ní Yaba College of Technology tí ìpinlẹ̀ Èkó ní Magboro ní Ìpínlẹ̀ Ògùn tí ọwọ́ ọlọ́pàá RRS ti tẹ̀ to n ṣàpatẹnu jẹ́wọ́.

Afurasí náà Olufowoke Oladunjoye Emmanuel ni wọ́n lọ gbé nílé àwọn òbí rẹ̀ lọ́jọ́bọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta ti wọ́n ti n ṣọ́ọ kiri.

Kọmísánà ìpínlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumosu sàlàyé pé ni kété ti ọ̀rọ̀ náà ti jẹyọ nínú oṣù kẹrin tí wọ́n mú ẹ̀sùn wá pé ẹnìkan fẹ́ bá Salawa Abẹni lórúkọ jẹ́ ní òun ti pàṣẹ fún ẹ̀ka RRS láti ṣe ìwádìí irú ẹni bẹ́ẹ̀.
Afunrasí ọ̀un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọlọ́pàá sàlàyé pé lóòtọ́ òun lòun wà nídìí ìbanilórúkọ jẹ́ náà láti gba owó díẹ̀ ní.

Àkẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ẹ̀rọ ní YabaTech ọ̀ún ní òun rí fótò ìhòòhò báàgì nínú káàdì ìránti kan ní ìlẹ̀ẹ́lẹ̀ nílé iwé òun ní ínu ọsù Kọkànlá ọdún 2019 ní.

Ó fí kún pé lẹ́yìn ti òun fi fótò náà si orí fóònù òun tàn, òun wá wá nọ́nbà Waka Queen lójú òpó Sítágíràmù rẹ.

Lẹ́yìn náà lòun fí àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí gbajúgbajà olórin náà lẹ́yìn ti òun fi àwọn fótò díẹ̀ sọwọ́ síi. Èrò ọkàn mi ni láti gba owó díẹ̀ kí n sì ba àwọn fótò náà jẹ́.

“Mo rò pé gbogbo nǹkan sì ńlọ bí mo ṣe rò ni àfi ti mó gbọ́ nínú ìròyìn lọ́jọ́ kejì pé ẹnikàn ń gbìyànjú láti bá òun lórúkọ jẹ́, ẹ̀gbẹ́ ìyá mi ni mo wà nígbà ti ìròyìn náà ń lọ lórí i Rédíò tí ìyá mi náà sì ń ṣépè lé ẹni tó fẹ́ ba Salawa lórúkọ jẹ́ láì mọ̀ pé, ẹmi gàn ni mo wà nídìí ọ̀rọ̀ náà”

” Mo rọra yọ́ jáde, mo sì lọ ba káàdì ìpè mi àti káàdì ìràntí náà jẹ́ tí mò sì júù sọnù ti fóònù sí inú omi kan ní Magboro, kò sì sí ẹni tó sọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà tàbí pe Alhaja Salawa lórí ọ̀rọ̀ náà mọ́”

Ẹ̀wẹ̀ gbájúgbàja olórin náà Salawa Abẹni ti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ní Nàìjíríà àti lókè òkun fún àdúrótì, bákan náà lo dúpe lọ́wọ́ àjọ ọlọ́pàá pàápàá jùlọ ẹka RRS fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe láti wá ọmọkunbrin náà jáde.

Salawa ní òun kọ́ ni ẹni àkọ́kọ́ tí ọmọkùnrin yìí ṣe irú rẹ̀ fún, sùgbọ́n òun dúpẹ́ fún ìfẹ́ àti àdúrótì gbogbo ènìyàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …