Home ÀKỌ̀TUN Auxiliary, ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú — Ìjọba Ọ̀yọ́ dúnkookò
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 2, 2020

Auxiliary, ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú — Ìjọba Ọ̀yọ́ dúnkookò

Auxiliary, ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú — Ìjọba Ọ̀yọ́ dúnkookò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó dà bí ẹni pé orí tí yóó súpó, kìí jẹ́ kí ti ọlọ́kùnrùn ó yè ni ọ̀rọ̀ fẹ́ dà báyìí fún asáájú ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àkóso gárèjì ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Alhaji Mukaila Lamidi, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Auxiliary.
Bí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe ń pa á lówe fún un pé ata dùǹdú rẹ̀ ń fínmú, àti pé pọnlá pọnlá a bàtá rẹ̀ yìí lè ya lójijì.

Nígbà tó ń fi ewé ọmọ mọ́ Auxiliary létí, Kọmísánà fún iṣẹ́ òde àti ìgbòkègbodò ọkọ̀ nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Raphael Àfọ̀njá ní etí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kún, lórí àwọn ìwà ìdàlúrú tí asáájú ìgbìmọ̀ alákòóso gárèjì ọkọ̀ àti àwọn ìṣọǹgbè tíí ṣe ọmọ lẹ́yìn rẹ ń hù nígboro.

Afonja, lásìkò tó ń kópa lórí ètò orí rédíò kan nílù Ìbàdàn ní, kò sí ẹni tí ìjọba kò leè pààrọ̀, yóó sì dáa kí Auxiliary àti ìṣọǹgbè rẹ so èwe gbejẹ mọ́ wọ́.
Ó ní àfojúsùn Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso Gómìnà Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ní pé kí ìdẹ̀rùn bá ìlú, láì sí páà héè.

“Etí ìjọba Ọyọ ti kún nípa ìwà ìpáǹle tí àwọn ọmọlẹ́yìn Auxiliary ń ṣe, mo wá ń fi àkókò yìí késí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti sinmi agbaja, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìjọba yóó gba ipò náà lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí kò sí ẹni tó ga ju òfin lọ.”

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ariwo ti sọ nígboro ìlú Ìbàdàn nípa bí àwọn ọmọlẹ́yìn Auxiliary ṣe ń hùwà ipá ní àwọn ibùdókò tí wọ́n ti ń ṣíṣẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…