Home ÀKỌ̀TUN Iró̩ kò dára, mo mo̩ e̩ni ti covid-19 pa ni Kogi- Dino Melaye
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 30, 2020

Iró̩ kò dára, mo mo̩ e̩ni ti covid-19 pa ni Kogi- Dino Melaye

Iró̩ kò dára, mo mo̩ e̩ni ti covid-19 pa ni Kogi- Dino Melaye
Yínká Àlàbí

Awon ajo NCDC ni pelu ayewo awon, covid-19 ti rapala wo ipinle Kogi sugbon ijoba ipinle naa ni iro ni won n pa.
Senetor Dino Melaye to je omo ipinle naa wa n so pe ko dara bi ijoba ipinle naa se n femi awon eniyan sere. O ni arun yii kii se ojo iku ti eniyan ba tete mura sii.
O ni oun mo eni ti ajakale arun yii pa ni kabba ni ipinle Kogi.
O ni ibi ti iro pipa ko ti dara, awon ebi oku gan-an mo pe covid-19 lo pa Chief Imam Kabba, Sheikh Ahmad Abubakar Ejibunu.
Dino Melaye ni oun gba ijoba ipinle Kogi ni imoran ko gba awon ajo NCDC laaye lati le se amojuto ati ayewo fun gbogbo awon ebi ati awon eniyan ti Imam naa ni asepo pelu.
Melaye ni awon ebi oloogbe naa mo pe lati igba ti won ti gbe baba naa kuro ni ile-iwosan nla kan lo si ti ijoba apapo (Federal medical centre) to wa ni Lokoja. O ni lati ibe , o tun di Abuja kelele ki abajade ayewo to gbee pe baba naa ni arun naa.
Melaye ni ibi ti oro naa ko ti see fi owo yepere mu ni pe baba naa ko lo irin ajo lo si oke okun lati ni ajosepo pelu eni to sese de. Ni eyi to tumo si pe adugbo ni baba naa to koo.
Senetor Dino Melaye ni oun ba ebi Ejibunu kedun pe Olorun ko ni je ki a ri iru re mo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…