Home ÀKỌ̀TUN Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pàrọ̀ àwọn kọmíṣọ́nà rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 29, 2020

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pàrọ̀ àwọn kọmíṣọ́nà rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pàrọ̀ àwọn kọmíṣọ́nà rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní a kìí ṣ’ọ̀rẹ́ èrò ká yọ̀, bó pẹ́ tí tí, kóówá ó re lé ẹ̀ , èyí ló díá fún bí Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Nàìjíríà, Mohammed Adamu ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n ṣí àwọn Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá kan nípò láti ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ sí òmíràn.

Agbẹnusọ ìléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Frank Mba ló fi ọ̀rọ̀ náà léde ní olú iléeṣẹ́ náà tó wà ní ìlú Àbújá.

Àwọn Kọmíṣọ́nnà ọ̀hún àti àwọn ìpínlẹ̀ tuntun tí wọn yóó ti máa ṣiṣẹ́ rèé.

Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun – CP Undie J. Adie

Ìpínlẹ̀ Edo – CP Johnson Babatunde Kokumo

Ìpínlẹ̀ Bauchi – CP Lawal Jimeta Tanko

Ìpínlẹ̀ Ebonyi – CP Philip Sule Maku, fdc

Ìpínlẹ̀ Gombe – CP Ahmed Maikudi Shehu

Ìpínlẹ̀ Òǹdó – CP Bolaji Amidu Salami

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ – CP Joe Nwachukwu Enwonwu

Eastern Port – CP Evelyn T. Peterside

EOD – CP Okon Etim Ene, fdc

Ìléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní pápákọ̀ òfurufú – CP Bello Maikwashi

Ẹ̀ka tó ń gbógun ti ìwà jẹgúdújẹrá ní ìpínlẹ̀ Èkó – CP Olukolu Tairu Shina

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà wá rọ àwọn Kọmíṣọ́nnà tuntun ọ̀hún láti rí i dájú pé wọ́n dáàbò bo àwọn agbègbè tuntun tí wọ́n ń lọ, ju ti àwọn tó ti ṣiṣẹ́ ṣaájú wọn níbẹ̀ lọ.

Lẹ́yìn náà ló rọ àwọn ará ìlú láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kí iṣẹ́ wọ́n le yọrí sí rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…