Home ÀKỌ̀TUN Èsì àyẹ̀wò tuntun, ìpínlẹ̀ **Kogi* ti káǹkóò Kofi 19.
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 28, 2020

Èsì àyẹ̀wò tuntun, ìpínlẹ̀ **Kogi* ti káǹkóò Kofi 19.

Èsì àyẹ̀wò tuntun, ìpínlẹ̀ **Kogi* ti káǹkóò Kofi 19.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní,bí ilé kò bá kan ilé , kìí jó àjóràn.
Ọ̀rọ̀ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ yìí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì ti di tọ́rọ́ fọ́nkálé, bí ó se ń tí ìpínlẹ̀ kan bọ́ sí òmí-ìn.

Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC, ti kéde pé àwọn tó ti ní àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà báyìí ti di ,ẹgberun mẹ̀jọ lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin àti mẹ́tàlélọ́gbọ̀n 8,733 ,

Ènìyàn 389 tuntun ni àkọsílẹ̀ wà pé ó ti ní àrùn náà, ó sì ti wọ ìpínlẹ̀ márùndínlógójì, àti ìlú Àbújá.

Ní báyìí, ìpínlẹ̀ *Kogi* náà ti darapọ̀ mọ́ àwọn ìpínlẹ̀ tí àrùn náà ti wọ̀ l’orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àlàyé rè é lórí ìpínlẹ̀ tí àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdi àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì tuntun náà ti wá:

Àbájáde Kofi 19 tuntun jẹ́ 389, ọ̀rìnléọ́ọ̀dúnrún lé mẹ́sàn án

Lagos-256, Katsina-23 ,Edo-22
Rivers-14, Kano-13
Adamawa-11,Akwa Ibom-11,Kaduna-7
Kwara-6,Nasarawa-6
Gombe-2, Plateau-2
Abia-2, Delta-2
Benue-2 ,Niger-2
Kogi-2, Oyo-2 ,Imo-1
Borno-1, Ogun-1
Anambra-1

Ṣùgbọ́n, èèyàn 2,501 ti rí ìwòsàn,
ọ̀tàlérúgba dín mẹ́fà 254 sì ti kú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn …