Home ÀKỌ̀TUN Agbẹ́bojì mẹ́rin jí òkú wú torí torí nílùú Àkúrẹ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 26, 2020

Agbẹ́bojì mẹ́rin jí òkú wú torí torí nílùú Àkúrẹ́

Agbẹ́bojì mẹ́rin jí òkú wú torí torí nílùú Àkúrẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó kú bọ́ lọ́wọ́ ọ làásìgbò ayé la gbọ́njú mọ̀. À mọ́, kò jọ pé ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ mọ́ o láwùjọ tá a wà yìí, tí ìwà ọ̀dájú kàn ń fojoojúmọ́ ayé gbilẹ̀ bí ọ̀wàrà òjò. Àgbọ́sọgbánù ìròyìn yìí ló ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọwọ́ ṣìkún àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òǹdó ti tẹ àwọn mẹ́rin kan tí wọ́n ká orí èèyàn mọ́ lọ́wọ́ nílùú Àkúrẹ́.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Tee-Leo Ikoro ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn .

Àwọn afurasí ọ̀hún tó jẹ́ Agbẹ́bojì ní ilẹ̀ ìsìnkú tó jẹ ti ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Àkúrẹ́ ni ọwọ́ pálábá wọn ṣégi níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti gé orí òkú kan tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀
Ẹni ti ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ pé àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé ọ̀hún padà wá sí ilẹ̀ ìsìnkú náà láti mọ odi lé ibojì rẹ̀, ni wọ́n bá ká àwọn kọ̀lọ̀rànsí ọ̀daràn ọ̀hún,mẹ́rin níye tí wọ́n ń làágùn yọ̀bọ̀, ní bi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti mú ìlérí èṣù sẹ nípa gígé orí òkú olókùú tí wọ́n sin ní wákàtí díẹ̀ sẹ́yìn.

“Lẹ́yìn tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n tán, ni a fi lílù gbe òkú níjà , nígbà tí a ká orí obìnrin kan àti àwọn orí èèyàn míràn mọ́ wọn lọ́wọ́.”
Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà sọ fún akọ̀ròyìn pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó ní “Ní kété tí wọ́n ké sí wa, ni àwọn òṣìṣẹ́ wa lọ sí ibẹ̀, tí a sì gbá àwọn ọ̀daràn náà mú ṣínkún lọ́rùn ọwọ́ pẹ̀lú orí èèyàn àti àwọn ẹ̀yà ara èèyàn míràn.

“Ní báyìí, a ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíkún láti mọ̀ bóyá àwọn kan ló rán àwọn ọ̀daràn náà níṣẹ́ dé tòru tòru tàbí iṣẹ́ ara wọn ni wọ́n ń jẹ́.”

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn afurasí náà yóó fojú bá Ilé ẹjọ́ wí tẹnu wọn ní kété tí ìwádìí bá tí parí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…