Home ÀKỌ̀TUN Márùnúnlélógójì èèyàn bọ́ lọ́wọ́ Kofi 19 nípìńlẹ̀ Èkó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 25, 2020

Márùnúnlélógójì èèyàn bọ́ lọ́wọ́ Kofi 19 nípìńlẹ̀ Èkó

Márùnúnlélógójì èèyàn bọ́ lọ́wọ́ Kofi 19 nípìńlẹ̀ Èkó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu ló fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lójú òpó Twitter ìpínlẹ̀ Èkó lọ́jọ́ Sátidé.

Gómìnà Sanwo-Olu ṣàlàyé pé mẹ́tàlélógún ni ọkùnrin nínú àwọn èèyàn náà nígbà tí méjìlélógún jẹ́ obìnrin.

Níbá yìí, ó ti di ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin èèyàn ó lé méje tí wọ́n ti jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì nípìńlẹ̀ Èkó.

Mọ́kàndínlógún nínú wọn ló gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn ìtọ́jú àjàkálẹ̀ àrùn tó wà ní Yaba, mẹ́ta láti Onikan, mẹ́jọ láti Agidingbi, nígbà tí ẹnìkan wá láti Etí Ọsa, ilé ìwòsàn LUTH làwọn méje tó kù ti wá.

Gómìnà rọ àwọn aráàlú ìpínlẹ̀ Èkó láti ran ìjọba lọ́wọ́ nípa gbígbógun ti ìtànkálẹ̀ àrùn Kofi 19.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…