Home ÀKỌ̀TUN Àjọ gómìnà ìpínlẹ̀ Nàìjíríà kò faramọ́ àpérò ọ̀pọ̀ èrò…. Fáyẹmí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 25, 2020

Àjọ gómìnà ìpínlẹ̀ Nàìjíríà kò faramọ́ àpérò ọ̀pọ̀ èrò…. Fáyẹmí

Àjọ gómìnà ìpínlẹ̀ Nàìjíríà kò faramọ́ àpérò ọ̀pọ̀ èrò…. Fáyẹmí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àìfẹ̀ṣọ̀ kébòsí, làì réèyàn dà gọ̀ọ̀rọ̀gọ̀. báni jó o.Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Dókítà Káyọ̀dé Fáyemí ti sísọ lójú rẹ̀ pé ìfilọ́lẹ̀ ikọ̀ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ló wà fún ìpèsè ètò ààbò tó jíire fún Ilẹ̀ Yorùbá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ fa ìkùnsínú láàrin àwọn Gómìnà ẹkùn káàárọ̀ o jíire.

Gómìnà Fáyemí, ẹni tó kéde bẹ́ẹ̀ lásìkò tó ń kópa lórí ètò kan, wá ṣẹ́ lórí àhesọ ọ̀rọ̀ tó ń jà rànìnrànìn pé òun fẹ́ du ipò Ààrẹ Orílẹ̀ yìí lọ́dún 2023, n l’òun ṣe ń ṣe kòkàárí ètò Àmọ̀tẹ́kùn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àrùn apinni léèmí Kofi 19 tó gbòde, àti ipa tí Ìjọba rẹ̀ ń kó láti ṣẹ́gun àrùn náà, Fáyemí ní kò sí ẹni tó lè sọ pé òun jàjàsẹ́gun lórí àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ.

Ó ní ohun kan ṣoṣo tó sì le borí àrùn ọ̀hún ni ìgbélé àti pé, kò sí bí àrùn náà ṣe le káṣẹ̀ nílẹ̀ pátápátá, yóó sì máa wà bíi HIV àti ọ̀fìkìn ni.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àtìlẹ́yìn tí wọ́n ń ṣe fún àwọn olóògùn ìbílẹ̀ lórí ìwòsàn àrùn apinni léèmí Kofi 19, Fáyemí ní ó se ni láànú pé òògùn òyìnbó la gbájúmọ́, kò sí ohun tó burú níbẹ̀ tí ìtọ́jú àrùn náà bá wá láti ọwọ́ àwọn olóògùn ìbílẹ̀ wa.

Ó ní àìmọ̀kan ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn kan máa rò pé arumọjẹ ní àrùn àjàkálẹ̀ Kòrónáfairọ̀ọ̀sì, ìjáfara sì léwu fún àgbàlagbà tó bá ní àrùn mìíràn lára tẹ́lẹ̀, tó bá tún ní àrùn yìí.

Fáyemí, tíí ṣe Alága ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà nílẹ̀ Nàìjíríà wá sísọ lójú rẹ pé, ní ọ̀pọ̀ ìpàdé tí àwọn ti ṣe ni àwọn ti fẹnu kò lórí àwọn ìgbésẹ̀ kan, tó fi mọ́ òfin pé ìrìnkèrindò ọkọ̀ ó di wápe, kò gbọdọ̀ wáyé láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn
Ó ní àwọn gómìnà kan ló ń pàṣẹ tó wù wọ́n ní ìpínlẹ̀ wọn

“Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà láti gbàdúrà fún àlàáfíà lórí àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì ló mú kí àwọn Gómìnà kan kéde pé kí àwọn mùsùlùmí lọ kírun ọdún ìtúnu ààwẹ̀, tí wọ́n sì tún fún àwọn Kírísítìẹ́nì láàyè láti ṣe ìsìn.”

Lórí ọjọ́ ọ̀la Nàìjíríà lẹ́yìn àrùn Kofi 19, Fáyemí ní ọjọ́ ọ̀la orílẹ̀-èdè yìí yóó dára nítorí ọgbọ́n tuntun ni àrùn náà fi ń kọ́ wa, tó sì yẹ ká gbájúmọ́ àmúlò ayélujára báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

“Ìgbà ìpọ́njú la má a ń ronú jinlẹ̀ jù, ara ohun tí yóó sì jẹyọ lára àrùn Covid-19 yóó mú ìdàgbàsókè bá wa, bí ilẹkún kan kò bá tì, òmíràn kìí sí.”
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ètò ìrànwọ́ tí Ìjọba rẹ̀ ń ṣe, Fáyemí ní òun máa ń fún àwọn arúgbó ní ẹgbẹ̀rún márùn ún náírà lósoosù, ọ̀dọ́ bíi ẹgbẹ̀rún márùn ún sì làwọn fún ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà ẹnì kọ̀ọ̀kan, tí òun sì tún fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó ìrànwọ́ ètò ẹ̀kọ́.

Fáyemí, lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lórí ajọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Èkìtì, Segun Oni, ó ní kò sí aáwọ̀ láàrin òun àti Oni, tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tẹ̀lé gómìnà àná náà sì wà nínú Ìjọba òun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…