Home ÀKỌ̀TUN Àgbà ọ̀jẹ̀ onítíáta ,Laditi jáde láyé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 25, 2020

Àgbà ọ̀jẹ̀ onítíáta ,Laditi jáde láyé

Àgbà ọ̀jẹ̀ onítíáta ,Laditi jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ikú ń pa ni, ilẹ̀ ń jẹ̀ẹ̀yàn . Ikú tún ti nawọ́jà rẹ̀ mú gbajúgbajà òṣèré tíátà kan ńlẹ̀ yìí, Ọmọba, Femi Oyewunmi tí ìnagijẹ rẹ̀ nínú eré ń jẹ́ Laditi rìrìn àjò láé láé ó di gbéré.

Ọ̀rẹ́ olóògbé náà, Ọ̀gbẹ́ni Sayo Alagbe ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn .

Ọmọba Oyewunmi ni a gbọ́ pé ó ti ń sàìsàn fún ọjọ́ pípẹ́, kódà Ọ̀gbẹ́ni Alagbe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ṣiṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀yìn rẹ.

Ó padà jẹ́ Ọlọ́run ní pè lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lọjọ Jimọ, ọjọ́ kejìlélógún oṣù karùn ún un ọdún 2020.

Olóògbé Oyewunmi kópa nínú àwọn eré tíátà bíi Ayé Tó tó, Kòtò Ọ̀run, Ìjà Eleye àtàwọn eré tíátà.

Ó tún kópa nínú eré Ogun O Jàlú Ogbomoṣo kí ó tó dágbére fáyé.

Ọmọba Femi Oyewumi fi ìyàwó àti ọmọ méje sí ayé lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …