Home ÀKỌ̀TUN Covid-19 so̩ Donald Trump di e̩lé̩sìn òdodo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 23, 2020

Covid-19 so̩ Donald Trump di e̩lé̩sìn òdodo

Covid-19 so̩ Donald Trump d

i e̩lé̩sìn òdodo
Yínká Àlàbí

oruba bo won ni “oro ko ba ojugun lo ni ohun ko leran lara”. Ajakale arun coronavirus to ti n ba orile aye wo iya ija lati ibere odun yi ti so Aare Donald Trump di elesin.
Gbogbo itu meje ti ode n pa ninu igbo ni orileede Amerika ti pa sugbon ti covid-19 ko ti ko lo. Orisiirisii oogun ni won ti po po lati koju arun naa sugbon ti gbogbo igbiyanju naa ja si pabo.
Orileede naa ni won ti ni eniyan to ni arun naa ju lagbaye, ibe ni awon eniyan to ku ti po ju.
America yii si ni gbogbo aye n woju re bii alagbara ju lagbaye, sugbon kokoro aifojuri yii ti wa so ilu naa di yepere. Orileede yii lagbara ati imo sayensi de bi wi pe ti ile riri (earthquake)ba fe sele ni aadota odun si asiko ti a wa yii, won maa mo. Won si ti see ri, kia ni won ti maa so fun awon olugbe adugbo naa ki won tete maa ko aasa won nitori ile riri naa.
Gbogbo asotele yii ni o si maa n wa si imuse, sugbon kokoro aifojuri yii ko, ko fi aye lorun sile, ko si ona abayo fun un ju eni ti Eledua ba ko yo lo.
Arun yi lo.mu ki orileede Italy lo da gbogbo oosa won sodo nigba ti arun naa fe run ilu won. Won ni gbogbo bi awon se bo orisa naa to, ko gba ilu sile lasiko isoro.
Ofin konile-o-gbele ti wa ni America lati igba ti arun naa ti wo odo won. Won se eto fun awon ara ilu ti jije ati mimu ko fi ni si isoro. Won seto ti awon to n san owo ile, owo ina,owo omi, owo afefe idana ati awon owo to ku ko fi ni nira fun awon olugbe ilu naa fun osu meta si asiko ti a wa yii.
Gbogbo igbiyanju Arun yii lo ja si pabo ni eyi ti o mu ki Aare kede re bayii pe ki awon ile ijosin gbogbo ni America naa bere si ni josin ki awon le ke pe Olorun papo lori isoro arun yii.
Trump tun ni awon eniyan feran lati maa ko ara po sin Olorun gege bi ona lati gbe isoro fo.
Eyi lo mu ki Aare Trump kede pe awon agbofinro ko gbodo fi owo sinkun ofin mu enikeni to ba n lo si Mosalasi tabi Soosi re lati opin ose yii lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…