Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ bàálù tó ń yọ́lẹ̀ kó èrò wọ Nàìjíríà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 18, 2020

Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ bàálù tó ń yọ́lẹ̀ kó èrò wọ Nàìjíríà

Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ bàálù tó ń yọ́lẹ̀ kó èrò wọ Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ogun tí yóó bá wọlé kóni, ọ̀nà la tií pàdé rẹ̀.
Ìjọba àpapọ̀ ti gbẹ́sẹ̀ lé ọkọ̀ bàálú kan tó ń kó àwọn arìnrìnàjò lòdì sí àṣẹ tó gbà láti máa kó àwọn ohun èlò ìtọ́jú lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi.

Bàálú náà tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Flair Aviation, tí olú iléeṣẹ́ rẹ̀ wà nílẹ̀ Gẹẹsi takò àṣẹ Ìjọba Nàìjíríà tó dá ìrìnkèrindò ọkọ̀ òfurufú dúró lọ́nà àti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí ọ̀hún.

Mínísítà iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìrìnàjò ọkọ̀ òfurufú ní Nàìjíríà, Hadi Sirika sọ lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ pé, wọ́n ti fi ṣìkún òfin mú àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ náà tí aje ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣì mọ́ lórí, wọ́n sì ti ń fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò.

Mínísítà náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìwà ìkà ni iléeṣẹ́ náà wù láti máa gbé èrò lásìkò yìí àti pé Ìjọba àpapọ̀ kò ní fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …