Home ÀKỌ̀TUN Èèyàn kan dèrò ọ̀run ní Madagascar lẹ̀yìn tó ṣàwárí àgbo Kofi 19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 18, 2020

Èèyàn kan dèrò ọ̀run ní Madagascar lẹ̀yìn tó ṣàwárí àgbo Kofi 19

Èèyàn kan dèrò ọ̀run ní Madagascar lẹ̀yìn tó ṣàwárí àgbo Kofi 19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àrùn la rí wò, kò séèyàn tó rí tọlọ́jọ́, ṣe , èyí ló díá fún ọ̀rọ̀ kan tí Ìjọba ilẹ̀ Madagascar ti kéde ẹni àkọ́kọ́ tó kú látàrí àjàkálẹ̀ àrùn Kofi 19 lórílẹ̀-èdè náà.

Wọ́n ní ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ọ̀hún, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera ti ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà àti ẹ̀jẹ̀ ríru lára tẹ́lẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ṣaájú ní Ààrẹ ilẹ̀ Madagascar, Andry Rajoelina ti kéde àgbo kan tó ní ó lágbára láti wo àrùn Covid-19 tó ń bá gbogbo ayé fínra, l’éyìí tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nílẹ̀ adúláwọ̀ sì ti ní kó fi ṣọwọ́ sí wọn.

Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù karùn ún ọdún 2020 ni àgbo náà balẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n àjọ tó ń rí sí ètò ìlera lágbàáyé, WHO ti kìlọ̀ pé kí àwọn èèyàn ṣọ́ra fún òògùn tí àwọn onímọ̀ nípa ètò ìlera kò bá fọwọ́ sí.

Èèyàn mẹ́rìnlélọ́ọ̀dúnrún ló ti lùgbàdi àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì lórílẹ̀-èdè ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…