Home ÀKỌ̀TUN Hèèmọ̀! Ọba Alayé àti ọmọ rẹ̀ fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀ l’Ọ́ṣun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 17, 2020

Hèèmọ̀! Ọba Alayé àti ọmọ rẹ̀ fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀ l’Ọ́ṣun

Hèèmọ̀! Ọba Alayé àti ọmọ rẹ̀ fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀ l’Ọ́ṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọwọ́ titẹ ọba Alayé kan, Ọba David Ogungbemi àti ọmọ rẹ̀, Idowu, fún pé wọ́n fi ipá bá ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́rìnlà kan lòpọ̀.

Ọba náà ni orí adé ìlú Iketewi, tó wà ní Ìjọba ìbílẹ̀ Obòkun, nípìńlẹ̀ Ọ̀ṣun.

A gbọ́ pé ọmọbìnrin náà ń gbé pẹ̀lú àbúrò bàbá rẹ̀, Esther Ogungbemi, n’ílù Ilare, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Ìròyìn sọ pé ìbálòpọ̀ tipá-tipá náà di oyún, èyí tó mú kí bàbá rẹ̀ lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Ṣùgbọ́n nígbà tó ń sọ̀rọ̀, alukoro fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Ọ̀ṣun, Opalola Yemisi, sọ fún akọròyìn pé lóòtọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó jẹ́ ọba nínú àwọn méjéèjì tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan.

“Ohun tó hàn sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni pé bàbá àti ọmọ ni wọ́n, àwọn méjéèjì ló ṣì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlà náà lò pọ̀.”

Bákan náà ló sọ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti parí ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n sì ti gbé wọn lọ sílé ẹjọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…