Home ÀKỌ̀TUN E̩ má tíì bè̩rè̩ ìpàgó̩ eré ní lílo̩ – Adewale Elesho̩
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 16, 2020

E̩ má tíì bè̩rè̩ ìpàgó̩ eré ní lílo̩ – Adewale Elesho̩

E̩ má tíì bè̩rè̩ ìpàgó̩ eré ní lílo̩ – Adewale Elesho̩
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Gbajumo osere fiimu agbelewo ti gbogbo eniyan mo si Adewake Elesho lo n parowa si awon egbe osere.
Baba yii gbo nigba ti awon osere n mura kankan pe awon fe bere si ni lo si ipago ere.
Elesho gba won ni imora pe yato si pe won lodi si ofin ijoba nipa ki onilegbele, ki opo eniyan ma si se duro po ni ibikankan. Won tun maa fi owo sofo.
Baba yii ni won saa mo pe oun kii se odomode elere, o ni owo maa wogbo nitori pe gbogbo awon to ba wa ni ipago gbodo lo ibomu.
O ni bawo ni awon ololufe awon se wa fe mo iyato ninu oba ati ijoye tabi pelu ara ilu. O ni pelu ibomu, eru ko le yato si iwofa.
O ni gbogbo awon ti won n pariwo oda owo ni ki won ni suuru, o ni suuru to lojo ni oro ajakale arun coronavirus to gba gbogbo aye kan.
Abala kan ninu awon osere ko fara mo arowa baba yii, nitori pe won tenumo asa “enu gbe, apo gbe”.
Alagba Elesho ni owo ti oun ni ni oun ti ya won yen, eni ti o ba wu ki o gbo, eyi ti ko ba si gbo, ohun ti o n wa ni idi ako isu, o seese ki won rii nidii isu ewura.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…