Home ÀKỌ̀TUN A tako àgbo Madagascar fún Kofi -19 —Ẹgbẹ́ apoògùn Nàìjíríà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 14, 2020

A tako àgbo Madagascar fún Kofi -19 —Ẹgbẹ́ apoògùn Nàìjíríà

A tako àgbo Madagascar fún Kofi -19 —Ẹgbẹ́ apoògùn Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹgbẹ́ àwọn apoògùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, PSN ti ní Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò kọ ibi ara sí àwọn òògùn abẹ́lé tí àwọn ènìyàn ń ṣe láti kojú àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Akọ̀wé àjọ náà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Dudu Emeka ló fi èrò rẹ hàn lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lórí Ìdí tí àwọn fi tako àgbo láti orílẹ̀-èdè Madagascar tí Ìjọba Nàìjíríà sọ wí pé àwọn ti fẹ́ gbà á láti kojú àrùn apinni léèmí Kofi 19.

Dudu Emeka ní àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n ní abẹ́lé ti ṣe àwọn òògùn tó le è kojú àrùn náà, àmọ́ Ìjọba àpapọ̀ kò tilẹ̀ fún wọn ní àǹfààní láti ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ bóyá ohun tí wọ́n le lò ni àbí bẹẹ kọ.

Wọ́n ní eléyìí tí àjọ tó ń ṣàkóso òògùn àti oúnjẹ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NAFDAC ń ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ jẹ́ òògùn tó ń kojú ikọ́ eléyìí tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àmì tó má ń fihàn pé ènìyàn ní àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Ó ní kìí ṣe pé àwọn le è darí ìjọba àpapọ̀ lórí ríra àgbo lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè Madagascar, àmọ́ àwọn fẹ́ kí ìjọba ṣe àyẹ̀wò àwọn òògùn tí wọ́n ti ṣe lábẹ́lé náà láti kojú àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Akọ̀wé àjọ náà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Dudu Emeka wá fikún un pé àwọn ti ṣe òògùn lábẹ́lé tó lè kojú àìsàn ẹjẹ, Sickle cell Anaemia, òògùn ikọ́ àti bẹ́ẹ̀ lọ.

Àmọ́ṣá NAFDAC nínú àtẹ̀jáde wọn, sọ pé, iléeṣẹ́ ẹnìkan péré ló ti gbé òògùn wá lábẹ́lé fún àgbéyẹ̀wò bóyá lóòtọ́ ni òògùn náà le ṣe àwòtán àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Àjọ NAFDAC wá fi àsìkò yìí késí àwọn apoògùn láti ṣiṣẹ́ kárakára lórí àti wá ọna àbáyọ sí àrùn apinni léèmí Kofi 19 ní Nàìjíríà, àti pé àwọn setán láti ṣe àyẹ̀wò àwọn òògùn tí wọ́n bá ṣe lábẹ́lé.

Ó ti fẹrẹ tó ẹgbẹ̀rún márùn ún ènìyàn tó ti lùgbàdì àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ènìyàn méjìdínlọ́gọ́jọ sì ti papòdà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…