Home ÀKỌ̀TUN Ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà méjì fẹ́ fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ N100m ràdájọ́ òdodo — Àjọ EFCC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 13, 2020

Ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà méjì fẹ́ fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ N100m ràdájọ́ òdodo — Àjọ EFCC

Ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà méjì fẹ́ fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀
N100m ràdájọ́ òdodo — Àjọ EFCC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgúdújẹrá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà EFCC ti dẹdò àwọn gbé ẹja ńlá pẹ̀lú àwọn ọmọ Ilẹ̀ China méjì tó gbìyànjú láti fún Ọ̀gá àjọ náà kan ní ọgọ́rùn mílíọ̀nù Náírà owo àbẹ̀tẹ́lẹ̀

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà tó wà ní Sókótó ló gbá àwọn kọ̀lọ̀rànsí méjéèjì yí mú, tí wọ́n sì ṣàfíhàn owó náà àti àwọn afurasí yí lójú òpó abánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook àjọ EFCC.

Nínú ohun tá a rí kà níbẹ̀, Ọgbẹni Meng Wei Kun àti Xu Koi fẹ́ fún ọ̀gá EFCC agbègbè Sókótó ní owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àádọ́ta mílíọ̀nù náírà tí wọ́n kó wá bá a, èyí tó jẹ́ ìdajì ọgọ́rùn mílíọ̀nù tí wọ́n fẹ́ fún un, kí ó ba à mẹ́numọ́ lórí ìwádìí kan t’ájọ náà ń se lórí iléeṣẹ́ wọn.

EFCC sọ pé àwọn ń se ìwádìí aṣemáṣe tí àwọn fura sí pé iléeṣẹ́ Zhonghao Nig. Ltd táwọn arákùnrin náà ń ṣiṣẹ́ fún mọ nípa rẹ.

Ìwádìí ọ̀hún níí ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àgbàse oní àádọ́ta biliọnu náírà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara gbé fún wọn láàrin ọdún 2012 sí 2019.

Nínú iṣẹ́ èyí tí EFCC ń tọ pinpin yìí la ti rí iṣẹ́ àgbàse ojú ọ̀nà láàrin ìlú bí Gummi, Bukkuyun, Anka àti Nassarawa tó fi mọ́ iṣẹ́ àgbàse gbigbẹ ẹ̀rọ kànga ìgbàlódé(borehole) mejidinláàdọ́sàn ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlà ní ìpínlẹ̀ náà.

A tún rí i kà nínú àtẹ̀jáde tí EFCC fi síta pé nígbà táwọn ọmọ Ilẹ̀ China yìí rí i pé àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà kò jáwọ́ nínú ìwádìí wọn, ni wọ́n bá nawọ́ àbá ọ̀nà àbáyọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ọgọ́rùn mílíọ̀nù náírà kí ọ̀rọ̀ náà le jẹ ròkun ìgbàgbé.

EFCC láwọn ṣe bí ẹni gbà láti juwọ́ sílẹ̀, ni wọ́n bá fi gbé ìdajì owó náà wá, tí wọ́n sì sèlérí láti mú ìyókù àdéhùn owó náà wá tí ọ̀rọ̀ bá yanjú.

Àwọn aṣojú iléeṣẹ́ náà méjì Meng Wei Kun àti Xu Kuoi ni wọ́n fi páálí gbé owó náà wá sí iléeṣẹ́ EFCC tó wà ní òpópónà pápákọ̀-òfurufú ní Sókótó.

Ọjọ́ Kọkànlá oṣù Karùn ún ni ọwọ́ tẹ̀ wọ́n.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…