Home ÀKỌ̀TUN Ibrahim Gambari gbò̩pá às̩e̩
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 13, 2020

Ibrahim Gambari gbò̩pá às̩e̩

Ibrahim Gambari gbò̩pá às̩e̩
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Ojogbon Ibrahim Gambari ni o ropo Abba Kyari to salaisi ni osu to koja. Lati igba naa ni Aare ko ti ni olowo otun mo.
Olowo-otun Aare ni o sum mo Aare ju. Ohun lo mo nipa aabo, ounje, alejo, ipade ati gbogbo ohun to ro mo Aare ati ileese Aare.
Ipo ti o lagbara ti o si se pataki ni orileede yii ni.Eyi lo mu ki awon igbimo se opolopo iwadii gidi lori eni ti ipo naa to si. Ojogbon Ibrahim Gambari ni Ifa mu. Oun ni awon igbimo ni o kun oju osuwon.
Awon igbimo ni oun ni osuwon re kun ju. Won ni o ti sise pelu Aare Buhari ri lasiko ologun. O ti sise ni orileede yii ati ni oke okun ti o si di awon ipo to lagbara mu eyi ti awon igbimo ni o se ise naa daadaa.
“Yoruba bo, won ni” oosa ti a ti mo tele san ju Angeli ti a kii n gburo re lo. Gbogbo eyi lo sise fun Ojogbon Ibrahim Gambari. Ilorin ni ipinle Kwara ni Ojogbon naa ti wa.
Akowe agba fun ileese Aare, Alagba Boss Mustapha se afihan Ojogbon Gambari lonii ninu ipade Ijoba apapo to maa n waye ni gbogbo ojoojo Ojo’Ru.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…