Home ÀKỌ̀TUN Oúnjẹ ọ̀fẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ yòó gbéraṣọ—Ìjọba àpapọ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 11, 2020

Oúnjẹ ọ̀fẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ yòó gbéraṣọ—Ìjọba àpapọ̀

Oúnjẹ ọ̀fẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ yòó gbéraṣọ—Ìjọba àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọ̀ba àpapọ̀ ti kéde pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ètò pínpín oúnjẹ nílé iwé alakọbẹ̀rẹ̀ ní ìpińlẹ̀ mẹ́rin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Mínísitia fún iṣẹ́lẹ̀ pajawiri ati ìdàgbàsókè amúlùdùn, Sadiya Umar Farouq ní Ààrẹ ti pa á lásẹ fún ilé iṣẹ́ òun lójúnà ati mú àdínkù bá ìsòro òunjé ti àwọn ènìyàn ń kojú.

Ó ní ìjọba àpapọ̀ yóó ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ tí ètò náà yóò ti wáyé láti mọ́ ọ̀nà tí wọ́n yóó gbé ètò náà gbà nítorí pé, gbogbo ẹnu ọ̀nà ilé iwé ló wà ní títì pa ní àsìkò yìí.

Farouq ní àwọn ìpínlẹ̀ tí yóó ti máa wáye ni Èkó, Ògùn, Kano àti Àbújá.

Ó fí kún un pé àwọn yóò fikùnlukùn pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ lórí bi oúnjẹ náà ṣe máa dé ọ̀dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé e wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…