Ẹ ti ẹnubodè, ṣọọsì àti mọṣáláṣí pa– Àgbáríjọ Dókítà
Ẹ ti ẹnubodè, ṣọọsì àti mọṣáláṣí pa– Àgbáríjọ Dókítà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ogun tí yóó bá wọlé kó ni , ọ̀nà láti í pàdé rẹ̀, díá fún àwọn ẹgbẹ́ àwọn dókítà ní Ghana, Ghana Medical Association ti kìlọ̀ fún Ìjọba Ghana pé kò gbọdọ̀ sí ẹnu bodè rẹ̀ rárá lásìkò yìí.
Kódà wọ́n tún ní kò gbọdọ̀ gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin kí àwọn èèyàn má a péjọpọ̀ rárá, nítorí ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
Wọ́n ní Ìjọba Ghana kò gbọdọ̀ ṣí ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́sálásí rárá lásìkò yìí nítorí pé ogun àjọ já ni ogun ìtànkálẹ̀ àrùn coronavirus dì báyìí láti orílẹ̀-èdè kan sí ìkejì
Àwọn tó ti lùgbàdì coronavirus ní Ghana ti di 4, 263 èèyàn nígbà tí wọ́n tún ṣẹ̀sẹ̀ rí àwọn àádọ́ta lé nígba èèyàn tuntun báyìí.
Àwọ́n tó ti kú ti di méjìlélógún báyìí pẹ̀lú àwọn mẹ́rin tuntun tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ kéde
Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ
Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…