Home ÀKỌ̀TUN Mẹ́wàá lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní Kofi-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 9, 2020

Mẹ́wàá lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní Kofi-19

Mẹ́wàá lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní Kofi-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní bí babaláwo bá ti ń kígbe ẹ̀fọ́rí àbaàdì,k’áláìsàn ó má nírètí mọ́.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti sọ pé mẹ́wàá lára àwọn òṣìṣẹ́ Ilé ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti lùgbàdi àrùn apinni léèmí Coronavirus.

Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Akin Abayomi ló fi ọ̀rọ̀ náà léde lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ lọ́sàn ọjọ́ Ẹtì.

Ó ní “Inu mí dùn láti sọ fun yín pé, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu, àti ìyàwó rẹ̀ , Joke Sanwo-Olu kò ní àrùn Kofi-19 lẹ́yìn tí wọ́n sàyẹ̀wò nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀tọ̀ .”

Ó tẹ̀síwájú pé “Mẹ́wàá lára àwọn òṣìṣẹ́ Ilé ìjọba tó wà ní Marina tí ní àrùn Kofi-19.”

Lẹ́yìn náà ni Kọmíṣọ́nnà ọ̀hún rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó láti tẹ̀lé gbogbo ìmọ̀ràn àjọ NCDC, bí i wíwọ ìbòmú àtàwọn nǹkan míì tó yẹ ní ṣíṣe lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…