Home ÀKỌ̀TUN Gomina Kogi gbéná wojú àjo̩ NCDC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 8, 2020

Gomina Kogi gbéná wojú àjo̩ NCDC

Gomina Kogi gbéná wojú àjo̩ NCDC
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Gomina ipinle Kogi, Alagba Yahaya Bello lo gbalejo awon ajo NCDC to n se amojuto arun ajakale coronavirus.
O gba awon alejo yii ni towotese. Laarin asiko perente ti awon ajo yii fi duro si ipinle naa ni Gomina ti bere si ni ri aleebu won.
O ni ko tona bi won se bere si ni ba awon eniyan oun bowo. O ni sebi awon naa ni won sofin pe ki a ma se maa bo ara wa lowo nitori ajakale arun naa. O ni bawo ni won se tun maa bo awon eniyan oun lowo?
Bi gomina se paa lase fun won niyen pe won ni lati wa ni isele fun ojo merinla, ti oun ba wa rii pe nnkankan ko se won ni oun to maa gba won laaye lati maa se itoju awon eniyan oun.
Gomina Yahaya Bello ni ko kuku si arun yii ni ipinle oun rara, oun ko si ni laju sile ki talubo woo.
Eyi lo mu ki awon ajo NCDC binu pada si Eko, won ni gomina ko tewo gba awon.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…