Home ÀKỌ̀TUN Owó epo bẹntiró láwọn ibùdó ìjápo dínkù (depot) sí N108 láti N113
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 7, 2020

Owó epo bẹntiró láwọn ibùdó ìjápo dínkù (depot) sí N108 láti N113

Owó epo bẹntiró láwọn ibùdó ìjápo dínkù (depot) sí N108 láti N113

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni tí eégún ń lé, kó gbìyànjú kó máa rọ́jú, ìgbà tó le koko ò níí pẹ́ dẹ̀rọ̀ fún gbogbo aláforítì tẹ́mìí rẹ̀ bá ṣẹ́kù. Àsamọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ló bí ìròyìn tó jáde pé,
Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè yìí ti kéde àdínkù owó epo bẹntírò kúrò ní náírà mẹ́taleláàdọ́fà náírà tó wà tẹ sí náírà mejidinláàdọ́fà náírà gẹ́gẹ́ bí iye tí wọn yóó máa ta jálá epo láwọn ibùdó ìgbépo gbogbo lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àtẹjáde kan tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí káràkátà owó epo lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, PPMC fi síta ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà wà láti túbọ̀ mú kí ọjà rẹ̀ túbọ̀ tà si ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ àjọ tó ń rí sí ìdíyelé owó epo lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, PPPRA gbé kalẹ̀ lórí iye tí wọ́n yóò máa ta epo lórílẹ̀-èdè yìí .

Ọ̀gbẹ́ni Musa Lawan, olùdarí àgbà iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìdúnàándúrà epo lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, PPMC, ti ó kéde ọ̀rọ̀ náà síta ni, ìgbésẹ̀ àdínkù owó epo láwọn ibùdó ìjápo gbogbo náà yóó mú kí wọ́n leè tètè ta omilẹgbẹ bílíọ́nù jálá epo tí wọ́n ní káàkiri àká wọn síta lówó tí kò ga ju ara lọ fáwọn oníbàárà rẹ̀.

Ó fi kún un pé lẹ́yìn tí wọ́n fojúwo bí ojú ọjọ́ ṣe rí lọ́jà epo ni wọ́n fi gbé ẹ̀dínwó náà kalẹ̀.

Àmọ́ṣá , ẹ̀dínwó tuntun yìí kò kan epo dísù.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…