Home ÀKỌ̀TUN Mẹ́rin nínú àwọn mọ́kànlá láti Sokoto tí wón mú l’Oyo ,ní àrùn Covid-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 7, 2020

Mẹ́rin nínú àwọn mọ́kànlá láti Sokoto tí wón mú l’Oyo ,ní àrùn Covid-19

Mẹ́rin nínú àwọn mọ́kànlá láti Sokoto tí wón mú l’Oyo ,ní àrùn Covid-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ogun tí yóó bá wọlé kó ni, ọgangan ọ̀nà la tií pàdé rẹ̀, ọ̀rọ̀ àgbà yìí ló jẹ́ fún wọn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí àṣírí àyẹwò Kofi 19 fi túu síta pé mẹrin nínú àwọn èèyàn mọ́kànlá tó ń ti ìpínlẹ̀ Sokoto bọ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn agbófinró mú lẹ́nu ibodè ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí Ọ̀ṣun gbé jombo àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Ẹni tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Taiwo Ladipo ló fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún léde fún àwọn oníròyìn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ó ní àwọn mẹ́rin náà ti wà ní ilé ìwòsàn tí wọ́n yà ṣọ́tọ̀ fún àwọn tó ní àrùn Kofi-19, èyí tó wà ní Olódó.

Lẹ́yìn ìtàkurọ̀sọ pẹ̀lú àwọn arìnrìnàjò náà, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé sọ pé òun kò ní yọ̀ǹda wọn fún Ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto, àyàfi tí wọ́n bá kọ́kọ́ sàyẹ̀wò àrùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì fún wọn.

Iye àwọn tó ti lùgbàdì àjàkálẹ̀ àrùn náà nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ lásìkò yìí jẹ́ mọ́kàndínlógójì, tí méjìdínlọ́gọbọ̀n nínú wọn sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mẹ́sàn án ti rí ìwòsàn, àwọn kan ti jẹ́ Ọlọ́run nípè látàrí àrùn ajániláyà pàtì ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…