Home ÀKỌ̀TUN Ẹ ṣílẹ̀kùn ọjà, ẹ t’ilé Ọlọ́run, howu ! Ejò lọ́wọ́ nínú – Oyedepo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 7, 2020

Ẹ ṣílẹ̀kùn ọjà, ẹ t’ilé Ọlọ́run, howu ! Ejò lọ́wọ́ nínú – Oyedepo

Ẹ ṣílẹ̀kùn ọjà, ẹ t’ilé Ọlọ́run, howu ! Ejò lọ́wọ́ nínú – Oyedepo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìlù u gángan lọ̀rọ̀ Ilé ayé jọ, n tó kójú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sẹ́lòmíìn ló bí àwọn gbólóhùn tó ń tẹnu
Oyedepo, ẹni tó pariwo lásìkò ìsìn wákàtí àdúrà tó wáyé ní Ọjọ́rú ní, òun fura pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí bí ìjọba kò ṣe tíì pàṣẹ láti ṣílẹ̀kùn ilé Ọlọ́run padà.

“Ẹ ní kí wọ́n máa ṣílẹ̀kùn ọjà gbogbo fún wákàtí mẹ́fà, kí wá ló dé tí ẹ kò fi sílẹ̀kùn sọ́ọ̀sì fún wákàtí méjì, mo ní ìgbàgbọ́ pé ìdìtẹ̀ mọ́ ìdàgbàsókè àwọn sọ́ọ̀sì ni Nàìjíríà ni èyí”.

“Mò ń fura púpọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ọlọ́run bá mi sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní àná, àbí ọ̀nà wo ni wọ́n tún fẹ́ gbà láti dá sọ́ọ̀sì lọ́wọ́ kò má baà gbòòrò, oyè èyí kò ye àwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ yìí kan.”

Oyedepo ní ohùn òkùnkùn ló fẹ́ ń darí àwọn èèyàn ní gbogbo ẹ̀ka yìí, tó sì dojú kọ ìjọ Ọlọ́run nítorí bí àwọn sọ́ọ̀sì ṣe ń gbòòrò ló ń fọ èṣù lórí, àmọ́ ẹnu ọ̀nà ọrùn àpáàdì kò ní borí, èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ yóò jìyà rẹ̀.

Oyedepo tún wà ń béèrè pé” irú ilé ìwòsàn wo ló ń ṣe àṣeyọrí ìwòsàn bíi èyí táwọn ìjọ Ọlọ́run ńṣe?.

Ó ní ilé ìwòsàn tí àwọn èèyàn ń kú sí wà ní ṣíṣí sílẹ̀ àmọ́ wọ́n ti ilẹ̀kùn ilé Ọlọ́run nítorí ìwà ìjẹgàba èṣù, èyí tí kò ní ìwòsàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…