Home ÀKỌ̀TUN Òsèlú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 6, 2020

Òsèlú

Òsèlú
Láti o̩wó̩ È̩dáò̩tò̩ Agbeniyi

Òṣèlú
Ó sè lù
Ìlù tí a bá sè dáada ní ṣe lù
Ìlú tí a fi awọ gidi sè ní ń jẹ́ ìlù
Ìlú tí ó bá ní ṣaworo ni ìlù gidi
Ó ṣè lú gidi
Ìlù tí a bá sè dáadáa ní ṣe ìlú gidi
Ìlú tí a sé jiná ní jẹ́ ìlú gidi
Ìlú tí àwọn igi rẹ̀ dára bí igi Ìlù gidi
Ìlú tí a bá ṣe dáadáa ni ijó ti lè wáyé
Ìlù tí a bá sè dáadáa ní dùn-ún lu tí wú ni lórí láti jó sí

Ó sè lù
Ó ṣè lú
Tí a bá ṣè lú gidi ni a lè jó níbẹ̀
Tí a bá sèlù gidi ni ó lè ṣeé jó sí

Ìlú ṣe pàtàkì
Ìlú ṣe kókó
Bí a bá ṣe se ìlù ìlú wa ni a ó ṣe ṣe ìlú wa
Síse ìlù wa jẹ́ bí a tí ǹ ṣèlú
Ìlù ló jé ojúnà fún ìlú

Igi tí a fi gbẹ́ ìlú ni à ń pe àwọn tí ńṣèlú wa
Ọwọ́ àwọn gbẹ́nà-gbẹ́nà tí ńṣèlú
Wa ni a ti ńgba òye tí a fi ń sèlù
Ìlú ni ìlù wa, ìlù wa ni ìlú wa
Bí a bá ba ìlú jẹ látaara bíbà’lù jẹ́
Àti tún ìlú wa se yóò nira púpọ̀
fún gbogbo àwọn onílùú
Ṣíṣe ìlú wa ṣe kókó bíi lílu ìlù wa
Kíni ìlù wá fẹ sọ́ náà ni kíni ìlú wa fẹ́ ṣe?
Ohun tí ìlú waa bá ń sọ ni ìlù wán sọ!

Ìlú, ìlú, sísèlù áti ṣiṣèlú jẹ́ ọ̀nà kán náà tí a fi lè wo
Kíni, tàbi tani wá
Ìlú wa yẹ kó dùn, kó dùn bí ìlù wa

Báwo ni a ṣe máa se ìlù wa?
Igi wo ni a fi ńgbẹ́ ìlú wa?
Àwọn gbẹ́nà-gbẹ́nà ìlú wa ti ń fi igikígi gbẹ́ igi ìlú wa
Ìlù ìlú wa ti n dún ní ìdún-kú-dùn-ún

Àwọn ará ìlú wa ti ń jó ijókíjó
Ijókíjó àwọn ará ìlú wa si ìlùkulù àwọn àyàn-àn
Ti ti íjo wa sí ẹ̀yìn ìlù, ìlù kìlù wa
ti fẹ́ di bárakú tí mú kí ìlú di ìlúkílùú

Òṣèlú jatíjàti ní sè’lú jálajàla
Igi rádaràda sì ni wọ́n fi gbẹ́ Òṣèlú ti ṣèlú bálabàla.

*Ẹdaọtọ Agbeniyi*
Lagos, Nigeria

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…