Home ÀKỌ̀TUN Gbajúgbajà akọ̀ròyìn NTA àti Gáàdìan lùgbàdì Kofi 19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 6, 2020

Gbajúgbajà akọ̀ròyìn NTA àti Gáàdìan lùgbàdì Kofi 19

Gbajúgbajà akọ̀ròyìn NTA àti Gáàdìan lùgbàdì Kofi 19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí a bá ń sọ́ orí olórí, à fi kí á kún fún àdúrà pé kí àwòdì o má yọ́ kẹ́lẹ́ jí ti olúwarẹ̀ gbé sálọ.Ó díá fún bí ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Katsina ti banújẹ́ lórí bi ọ̀kan lára wọn, gbajúgbajà akọ̀ròyìn n nì, Ayinde Soaga, se lùgbàdì àrùn Kofi 19, nígbà tí akọ̀wé ẹgbẹ́ akọròyìn ẹ̀ka Sókótó Meya kúkú u kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí .

Soaga tó tún jẹ́ ọ̀ga àgbà Ilé ìṣẹ amóhùnmáwòrán Nàìjíríà, NTA Katsina ni ẹgbẹ́ náà sọ nínú àtẹ̀jáde pé àyẹ̀wò fihàn pé àrùn ajániláyà pàtì ọ̀hún Covid-19, tí ta kóró wọnú àgọ́ ará rẹ.

Púpọ̀ àwọn akọ̀ròyìn ni ó wà nínú ewu àrùn apinni léèmí yìí ní Nàìjíríà nípaṣẹ̀ lílọ bíbọ̀ láti lè se àkójọpọ̀ ìròyìn fáráyé gbọ́.

Alága ẹgbẹ́ náà, Tukur Dan Alli, sọ pé àsìkò yí làwọn akọ̀ròyìn nílò ìrànwọ́ Ìjọba àti àwọn aládàáni láti le dáàbò tó péye bò wọ́n, lórí iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò.

Ó késì ìjọba àti àwọn tí ó lẹ́nu lọrọ lẹ́ka ìròyìn láti pèsè irinṣẹ́ ìdáàbòbò ẹni àti àwọn nǹkan míràn tó le kó àwọn akọ̀ròyìn yọ lọ́wọ́ àrùn ajániláyà pàtì Covid 19.

Ọmọ bíbí Ẹ̀gbá Gbagura ni Ayinde Soaga jẹ́ nípìńlẹ̀ Ògùn.

Èèyàn méje ló ti dèrò ọ̀run nípaṣẹ̀ Covid 19 nípìńlẹ̀ Katsina tó jẹ́ ìpínlẹ̀ tí Ààrẹ Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti wá.

Lósù kẹta ọdún yìí ni wọ́n kéde ẹni àkọ́kọ́ tó sàfihàn àrùn yìí.

Láti ìgbà náà di àsìkò yìí, àwọn mẹtàlélọ́gbọ̀n ló ń gba ìtọ́jú ní iléèwòsàn lórí àrùn apinni léèmí yìí tí ìròyìn sì sọ pé mẹ́fà lara wọ́n ti yá, lẹ́yìn táyẹ̀wò ní kò sí àrùn náà lára wọn mọ́.

Bákan náà ní ìròyìn tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àkọ̀wé àjọ náà Meya tí dágbére fayé.
Ọrọ yìí ni ọ̀gbẹ́ni Abubakar Awwal fí léde pé akọ̀wé ilé ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn náà ẹ̀ka ti Sòkòtò ti fayé lẹ̀ . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyẹwò Kofi 19 tí wọ́n se fún un kò tíì jáde, síbẹ̀, àbájáde àyẹwò ọ̀hún fihàn pé olóògbé ní àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Alága ẹgbẹ́ akọròyìn níbẹ̀,lsa Abubakar Shuni ti sàpèjúwe ikú akọ̀wé ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn náà bíi àjálù ńlá fún gbogbo akọ́sẹ́mọsẹ́ akọròyìn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…