Home ÀKỌ̀TUN Àwo̩n ará ìpínlè̩ Èkó fajúro si àìrówó gbà ní báǹkì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 6, 2020

Àwo̩n ará ìpínlè̩ Èkó fajúro si àìrówó gbà ní báǹkì

Àwo̩n ará ìpínlè̩ Èkó fajúro si àìrówó gbà ní báǹkì
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Ajakale arun to se gbogbo olugbe Eko, Ogun ati Abuja mole fun ose marun-un ti so opo eniyan di alailowo lowo mo.
Awon kan ko tile ni owo nile ati ni ile ifowo-pamo-si. Awon to ni senji die ati awon to ni eyi to gbera die ni won ti bere si ni paara ile ifowo-pamo-si lati ojo Aje ti ijoba apapo ati ti Eko ti de konile-o-gbele, titi di oni ojo ‘ru, ero pitimu naa lo si wa ni awon banki Eko.
Ero pitimu ni lati ojo Monde ti awon onibara ti n paara awon banki gbogbo ni ipinle Eķo.
Eru wa bere si ni ba awon eniyan kan pe se aabo to peye si wa fun owo awon bayii.
Iberu kekere lo tile wa ku fun Covid-19, nitorì pe awon eniyan sin ara won wole awon banki gbogbo ni ipinle Eko ni.
Awon kan tile ni aisi owo ninu awon banki kan lo je ki kaadi ATM maa ha sinu re.
Iwadii IROYIN OWURO fihan pe ko si ewu kankan fun awon owo wonyi ni ile ifowo-pamo-si, ero to jade leekan naa lo po ju ohun ti awon banki yii maa n ba pade tele.
A tun rii pe ofin ti ile ifowo-pamo-si agba (CBN) fi de iwe sowedowo lasiko isede naa wa lara wahala ati ero repete naa.
Eledua lo le gba wa ninu ajakale arun naa nitori bi awon eniyan ipinle Eko se tu jade lowo kan naa lewu die.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…