Tambuwal ké gbàjarè lórí Covid 19 ní Sokoto
Tambuwal ké gbàjarè lórí Covid 19 ní Sokoto
Fẹ́mi Akínṣọlá
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bá a se ń pà kan, lòmíì
Gómìnà Aminu Tambuwal tó ń tukọ̀ Ìpínlẹ Sokoto ti ke gbàjarè síta lórí iye àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ rẹ̀ tó ń lùgbàdi àjàkálẹ̀ àrùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì báyìí.
Ó ní láti ọjọ́ Àìkú ni wọ́n ti ń lé síi ní èyí tó n kọ òun lóminú.
Báyìí, ó ti kéde òfin kónílé-ó-gbélé láti aago mẹ́jọ sí aago mẹ́fà ìdájí.
Bákan náà ló tún rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti túbọ̀ ní ìmọ́tótó dáadáa lásìkò yìí pẹ̀lú títa kété síra ẹni
Tambuwal rọ ìjọba àpapọ̀ láti dìde sí ìrànlọ́wọ́ Sokoto lórí ohun èèlò àyẹ̀wò, ki ìtànkálẹ̀ àrùn náà le dínkù.
Báyìí, ó ti di èèyàn mẹ́rìndínláàdọ́rin tó ti ní àrùn apinni léèmí Kofi 19.
Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC
Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…