Home ÀKỌ̀TUN Ilẹ̀ Amẹrika dá $311m owó Abacha padà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 5, 2020

Ilẹ̀ Amẹrika dá $311m owó Abacha padà

Ilẹ̀ Amẹrika dá $311m owó Abacha padà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò sí irọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tó ṣọ pé, òmùgọ̀ ẹ̀dà ń kó ọrọ̀ jọ láì ní òye ẹni tí yóó lò ó.
Ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti dá okòóléọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́sàn (311) mílíọnu dọ́là owó tí wọ́n tí wọ́n ní Ààrẹ Orílẹ̀ yìí àná, Ọ̀gágun Sani Abacha lù ní póńpó padà fún Ìjọba Nàìjíríà.

Adájọ́ àgbà Nàìjíríà, Abubakar Malami fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹjáde kan tí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì ní ọ́fíísì rẹ̀, Umar Gwandu fi léde.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, ó ní iye owó náà lé sí i pẹ̀lú nǹkan bí i mílíọ̀nù méjì dọ́là láti ọjọ́ kẹta oṣù kejì títí di ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2020.

Malami sọ pé akitiyan láti gba owó ọ̀hún ni ìgbésẹ̀ rẹ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 2014, ṣùgbọ́n ilẹ̀ méjéèjì tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn lọ́dún 2018.

Lẹ́yìn náà ló fi dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú pé ìjọba yóó jẹ́ kí àwọn ará ìlú mọ ìlànà bí ìjọba yóó ṣe ná owó náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …