Home ÀKỌ̀TUN Oyetola bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀ lórí ìgbélé àrùn Covid-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 4, 2020

Oyetola bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀ lórí ìgbélé àrùn Covid-19

Oyetola bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀ lórí ìgbélé àrùn Covid-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun tí dẹkùn àṣẹ konile ó gbé lé ọlọsẹ méjì ni ọrùn àwọn èèyàn jákèjádò Ìpínlẹ̀ náà.

Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun fi gbé ìgbésẹ náà, Gómìnà Adegboyega Oyetola, nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà sọ ṣàlàyé pé, didẹ okun lọrun àṣẹ konile ó gbélé náà yóò mú kó rọrùn fáwọn aráàlú láti máa ṣíṣẹ oojọ wọn.

Kókó mẹ́wàá tó jẹyọ rèé nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ ọ̀hún sọ.

Alẹ́ ọjọ́ Àìkú ni òfin kónílé ó gbélé tó wá nílẹ̀ yóò wá sópin

Láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrin oṣù karùn-ún, ìjọba yóò dẹkùn lọ́rùn àṣẹ kónílé ó gbélé, tí àwọn aráàlú yóò sì ní àǹfààní láti rìn láàárín ìlú bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́fà àárọ̀ sí márùn-ún ìrọ̀lẹ́.

Láàárín ọjọ́ Ajé sì Ọjọ́bọ si ni àwọn èèyàn ní anfaani lati lọ si ẹnu isẹ Ajé wọn, tí ìjọba náà yóò sì leè ṣíṣẹ ìlú.

Òfin to de ìpéjọpọ̀ sì wá síbẹ̀. Kò sí gbọdọ si ìpéjọpọ̀ ọpọ èrò ni àwọn ilé ìjọsìn gbogbo, tàbí nílé ìwé, agbo òṣèlú àti níbi kibi.
Bákan náà, Oyetola ni gbogbo àwọn ọjà si lọ gbọ́dọ̀ wà ní títì pa.

Àwọn ibùdó itaja si lo gbọ́dọ̀ pèsè ọ̀sẹ̀ ifọwọ àti omi fáwọn onibara wọn
Ibùdó itaja ìgbàlódé taa mọ si Supermarket, kò gbọ́dọ̀ ni ju èèyàn mẹ́wàá lọ ní ẹẹkannaa

Gbogbo ààlà ibodè Ìpínlẹ̀ Osun pẹlu awọn Ìpínlẹ̀ tó mule tíì ní yóò sì wà ní títì pá, tí kò sì ní si lílọ bibọ ọkọ àti èrò àyàfi àwọn ọkọ akẹru tó ń kó oogun, oúnjẹ, èròjà epo rọbi àti ohun ọ̀gbìn nìkan ni yóò rí.
Àwọn ọlọkọ èrò yóò leè ṣíṣẹ ni aarin ìgboro láti ọjọ́ Ajé si Ọjọ́bọ ni ọsọọṣẹ, bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́fà àárọ̀ si márùn-ún irọlẹ, tí wọ́n ko si gbọdọ gbé ju èrò méjì si ìlà ijoko kọ̀ọ̀kan lọ nínú ọkọ wọn.

Gomina Oyetola wa kadi ọ̀rọ̀ rẹ nilẹ pé ọlọkada kan kò gbọ́dọ̀ gbé ju èrò kan ṣoṣo lọ, tí àwọn onikẹkẹ Maruwa kò sì gbọ́dọ̀ gbé ju èrò méjì lọ sí ẹyin ọkọ wọn nígbà tí kò gbọ́dọ̀ sì èrò kankan ní ijoko iwájú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…