Home ÀKỌ̀TUN Kò sí lílọ-bíbọ̀, Mò ń gbé l’Ogun, mo j’òṣìṣẹ́ l’Ekoo — Dapo Abiodun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 4, 2020

Kò sí lílọ-bíbọ̀, Mò ń gbé l’Ogun, mo j’òṣìṣẹ́ l’Ekoo — Dapo Abiodun

Kò sí lílọ-bíbọ̀, Mò ń gbé l’Ogun, mo j’òṣìṣẹ́ l’Eko–Dapo Abiodun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní ojú ni alákàn fií ṣọ́rí, àti pé ogun tí yóó wọlé kó ni , ọ̀nà la tií pàdé rẹ̀. Èyí ló díá fún bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun ti kéde pé kò ní i sí firi jangan lílọ bibọ̀ ọkọ̀ fún àwọn aráàlú tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ náà, ṣùgbọ́n tó ń ṣiṣẹ́ nípìńlẹ̀ Èkó.

Gómìnà sọrọ yìí ní ìlàkalẹ̀ bi agbara òfin kónílé-ó-gbélé yóó ṣe dínkù lọ́sẹ̀ yìí, lẹ́yìn tí Ààrẹ Muhammadu Buhari pàṣẹ rẹ̀.

Nínú ìkéde náà tí Gómìnà Àbìdun fi síta lórí ayélujára fesibúùkù lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ó sọ pé ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Karùn -ún ni òfin kónílé-ó-gbélé yóó káṣẹ ń lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ọjọ́ Ajé ni ìjọba àpapọ̀ pá á láṣẹ pé kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn, àti ìlú Àbújá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …