Home ÀKỌ̀TUN Ìbà Elédùà

Ìbà Elédùà

Ìbà Elédùà
Láti o̩wó̩ È̩dáò̩tò̩ Agbeniyi

*Ìbà Elédùà*
Mo wo òréré ayé títí
N ò rí ohun tó ṣe folú wé
kìkìdá ọlá, kìkìdá iyì òun ẹ̀yẹ
Ẹni mímọ́, ẹni ọlà tó dá ohun tó
dá gbogbo wa
Ẹni mímọ́ adákẹ́dájọ́
A wọ́ pooro ikú yè

Pàkùlà kan gbòòrò tí ró gbogbo ayé
Ìdìmú gbàǹgbà, hílàhílo ọmọ adáríhurun
Ẹni mímọ́ tó dá agbára tí alágbára fi dojú
ìjà kọ aláìlágbára tí ń fi agara dá aláìlágbára lágaara.
Èèkàn gbòǹgbò tí fìkà joyè
Ẹni mímọ́ tí ò ṣe fi wé ohunkóhun
Sáré má jà, má jà sáré Olú ló mọ ohun
Tó fi kóówá mọ, èrò odò ọkàn adáríhurun ò
K’olú, Ó ti mọ jìnísa ní déédéé kóówá

Ẹni òkè òun ilẹ̀, gegele òun ọ̀gbun
Sánmà òun Òfurufú, kòtò gìrìwò òun àfonífojì
Ọba lọ súà, ìjòyè pọ̀ bìbà
Olú ló mọ ẹni tí bá ṣè ‘jọba ayé
Èdùmàrè ló mọ àwọn tí í ba ṣè ‘jọba ọrùn
Ẹni funfun gbòò bí ayé mọ́
Ó dúdú họhọ bí òórùn dí

Kò sẹ́ni t’ Elédùmarè yé
Àkàwé ohun tólú jẹ́ ò yé èèyàn kankan
Ìbà adáríhurun ò kan Olú
Olú ló mọ ohun tó ń jó òun lára
Elédùmarè ó lórúkọ rẹpẹtẹ
Olódù tó màrè, Olódù tó màre
A dákẹ́ dájọ́ ẹni tí wo kóówá wa

Ẹni mímọ́ tó dá ìwà, Ó dá ẹni tí ń hùwà
Ọlá agbára ọlá, ọlà agbára ọ̀la
Ẹni tó dá ìbẹ̀rẹ̀ òun òpin
Iye ayé tó wà Elédùà ló mọ̀
Ọ̀run ò ṣe é kà à mọ́ Ẹni ọlá ló yé

Adára lolú, A burú lolú
Ìhà tólú bá kọ́ sọ́mọ èèyàn láá fọ̀
A lápa dúpẹ́, a han ni léèmọ̀ ore
A foore tún lé ayé ẹni ṣe
Ìmíì a jọ̀kà ló jú èèyàn
Adára tóó wùn!
Ẹni tí fojoojúmọ́ ṣe ohun tó dára fún ara rẹ̀
Èèkàn ńlá tí kò lóríkì.
A jírẹ̀bẹ̀!
Ìbà Elédùmarè!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …