Home ÀKỌ̀TUN Covid 19 gbẹ̀mí èèyàn mìí l’Ọ́sun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 3, 2020

Covid 19 gbẹ̀mí èèyàn mìí l’Ọ́sun

Covid 19 gbẹ̀mí èèyàn mìí ní l’Ọ́sun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn kan ti jẹ́ Ọlọ́run nípè nítorí àrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, nígbà tí ẹni tó ni àrùn ọ̀hún àti àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera mẹ́ta míì rí ìwòsàn gbà.

Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ náà, Rafiu Isamotu sọ pé olóògbé ọ̀hún tó jẹ́ ọmọ àádọ́rin ọdún dín díẹ̀ gbẹ́mìí mì ní ilé ìwòsàn Ìjọba Asubiaro, ní ìlú Oṣogbo.

Isamotu ní ìjọba gba èsì àyẹ̀wò ẹni àkọ́kọ́ náà àti àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó ri ìwòsàn lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì.

Ó ní ìlú London ni ẹni àkọ́kọ́ tó ní àrùn ọ̀hún ní Osun ti wá, ṣùgbọ́n ara rẹ̀ ti dá ṣáká báyìí lẹ́yìn tó lo ọjọ́ méjìdínlógójì níbi tó ti gba ìtọ́jú.

Lọwọ́lọwọ́ yi, èèyàn mẹ́jọ ni àrùn Covid-19 ń bá fínra ní Osun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …