Home ÀKỌ̀TUN Mó gbé okúta léna bí i oúnjẹ fáwọn ọmọ ọ̀ mi lórí òfin Covid 19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 1, 2020

Mó gbé okúta léna bí i oúnjẹ fáwọn ọmọ ọ̀ mi lórí òfin Covid 19

Mó gbé okúta léna bí i oúnjẹ fáwọn ọmọ ọ̀ mi lórí òfin Covid 19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bí n tí a mọọ jẹ bá tán, n tí a kìí jẹ ó má ṣàfira ní .
Bẹ́ẹ̀ wọ́n ní ọgbọ́n kò ní tán nínú àgbà kò má rí mí ìn dá ló dífá fún obìnrin kan ti wọ́n pé orúkọ rẹ̀ ní Kisauni lórílẹ̀-èdè Kenya bí ó se ló ọgbọ́n inú gbé òkúta léna tí ó sì ń koná mọ́ ọ, nítorí kò sí oúnjẹ kankan tí yóó fún àwọn ọmọ náà jẹ ,ó ní igbe ó pọ̀ bí wọn ò bá rí kí nǹkan wà lórí iná.

Kasauni ọlọ́mọ mẹ́wàá tó tún jẹ́ opó ní, láti ìgbà tí ìgbélé àrùn apinni léèmí Coronavirus ti bẹ̀rẹ̀ ni ó ti nira fún òun láti bọ́ àwọn ọmọ wònyí .

Ó ní inú oyún oṣù méjì ni òun wà nígbà tí ọkọ òun kú ní ọdún tó kọjá lásìkò ti àwọn ọ̀daràn gún un pa.

Ó ní òun ní láti gbé nǹkan kaná kí àwọn ọmọ fi ọkàn sí i pé oúnjẹ ń bọ̀, sùgbọ́n ìrètí òun ni pé, wọ́n ó sùn lọ.

Aládùgbóò Kisauni ló gbọ́ ohùn ọmọ rẹ̀ tó ń sunkú àsun-ùn-dákẹ́ ló fi bèèrè pé kí ló ṣe ọmọ náà, ìgbàyí ni ó wá gbé ìṣòro arábìnrin yìí s’órí itàkùn ayélujára.

Ní báyìí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ti ń wá láti ran obìnrin náà lọ́wọ́ pẹ̀lú onírúurú oúnjẹ àti nǹkan ìrànwọ́ mìíràn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…