Ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ ò dáwọ dúró lórílẹ̀-èdè Spain o
Ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ ò dáwọ dúró lórílẹ̀-èdè Spain o
Fẹ́mi Akínṣọlá
Wọ́n ṣì ń ka òkú lórí òkú lọ ni ní ìlú Spain.
Ó ti lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000) báyìí.
Iṣẹ́ ńlá l’àwọn tó ń ka òkú èèyàn ń ṣe lórílẹ̀-èdè Spain níbi tí òǹkà àwọn tí àrùn apinni léèmí coronavirus pa ti lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún.
Ọ̀pọ̀ ìbéèrè l’àwọn tó ti pàdánù ẹbí wọn ń bèèrè báyìí lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Spain.
Ó ṣì ń ṣe ọ̀pọ̀ ní kàyééfì bí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ tí arun covid-19 fi ṣekúpa àwọn ẹbí wọn.
Èèyàn méjìdínláàdọ́ta ní ìròyìn sọ pé ó kú sí ilé ìwòsàn àdáni kan, Monte Hermoso tó wà nílùú Madrid.
Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé àì ṣètò ìyara ẹni ṣọ́tọ̀ tó mọ́yán lórí, àìtó àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera àti àìsí ohun èèlò ìdáàbòbò ló ṣokùnfà àwọ́kú nílù náà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó gbékuru gàjà yìí ni wọn kò bá rùú là.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…