Home ÀKỌ̀TUN Ikú di tọ́rọ́ fọ́nkálé nílùú Kano
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 30, 2020

Ikú di tọ́rọ́ fọ́nkálé nílùú Kano

Ikú di tọ́rọ́ fọ́nkálé nílùú Kano

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọwọ́ tó bá ń duni, ẹnìkan kìí kí b’abẹ́ àgbádá ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí o, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Ganduje ti múgbe bọnu pé ìjọba àpapọ̀ gan an lọ́wọ́ sí bí wàhálà àrùn apinni léèmí Coronavirus ṣe ń gogò síi ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Ganduje ní ń ṣe ni ikọ̀ amúṣẹ́yá ti Ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ lórí gbígbógun ti àrùn apinni léèmí Coronavirus lórílẹ̀-èdè- Nàìjíríà, ,dẹ́yẹsí ìpínlẹ̀ Kano lásìkò tí àrùn náà búrẹ́kẹ́ sí i báyìí.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹlu akọ̀ròyìn, Gómìnà Ganduje ní bí ọ̀rọ̀ ṣe ń fojoojúmọ́ burú síi ní ìpínlẹ̀ Kano

Ó ní kò ṣẹ̀yìn bí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí Ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ lórí àrùn apinni léèmí COVID-19 ṣe kùnà láti mójútó ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Kano.

Ó ní òun fi ọ̀rọ̀ tó àwọn aláṣẹ Ìjọba àpapọ̀ títí kan ìgbákejì Ààrẹ létí pé iná wàhálà àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Coronavirus ń jó hèù hèù ní Ìpínlẹ̀ Kano ṣùgbọ́n kò sí ohunkóhun tí òhun rí gbọ́ padà lórí rẹ̀.

Ó ní ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ pé wọ́n ní láti ti ibùdó àyẹ̀wò kan ṣoṣo tó wà ní ìpínlẹ̀ náà fún àyẹ̀wò árùn Coronavirus fún ọjọ́ mẹ́fà gbáko.

Àmọ́ṣá , ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá lórí gbígbógun ti àrùn apinni léèmí coronavirus lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní kò s’óhun tó jọ .

Àti pé akọ́sẹ́mọsẹ́ mẹ́tàdínlógún ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí ìpínlẹ̀ Kano láti ṣe ìrànwọ́ lórí gbígbógun ti ìtànkalẹ̀ àrùn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…