Home ÀKỌ̀TUN Faye̩mi fè̩bùn dá bàbá tó le o̩mo̩ padà torí covid-19 ló̩lá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 30, 2020

Faye̩mi fè̩bùn dá bàbá tó le o̩mo̩ padà torí covid-19 ló̩lá

Faye̩mi fè̩bùn dá bàbá tó le o̩mo̩ padà torí covid-19 lola
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Baba kan, Femi Adeoye lo da omo re okunrin to sese ti ilu Eko de pada. Alagba yii ni oun ti so fun unn ki o duro si Eko ti rotiroti coronavirus se maa kuro Nile. Omo yii ko gbo, eyi si mu ki baba lo tele dee lodo awon ajo NCDC to wa ni ipinle Ekiti.
Baba yii fun awon ajo yii ni nomba omo naa ki won pee ki won si mu si odo fun ojo merinla ki oun to le gbaa sile.
Ere ni omo naa ati awon ajo NCDC koko pee nigba ti won ranse si baba pe ko si nnkan to se omo naa.
Alagba Adeoye ko jale pe ko le tele oun lo ile afi leyin ojo merinla tin oun ba rii pe ko si ajakale arun naa lara re.
Fidio yii ni o rin titi ti o fi de odo gomina ipinle Ekiti, Alagba Kayode Fayemi, eyi mu ki gomina ranse pe baba naa, o si soo di asoju gidi (Ambassador) fun ajo covid-19 ti ipinle Ekiti nibi ti gomina gan-an ti je olori ajo naa.
Gomina ni baba naa jewo omo oko Ekiti ti o ni ooto to o si feran ilu re.
Fayemi pe baba naa si ofiisi re pelu ami eye naa, o si ni ki awon ajo naa gba omo si ibi Kan fun ojo merinla. Fayemi ni oun ni igbagbo pe omo naa ko tii ko arun naa, o ni bi o si koo, o maa gba iwosan ti ara re si maa ya.
“Ori lo kuku n se ni ti a fi n dade owo, ori naa ni se ni ti eniyan fi n wewu oye” ori lo ko ire ba baba ti opo eniyan n pe ni alagidi. Won ni bawo lo se maa le omo re sita? won ni baba naa ko ki n se Yoruba tooto, nitori pe Yoruba bo won ni” omo buruku ko se le fekun paje”.
Ki ori gbe alawoore ko koowa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …