Home ÀKỌ̀TUN Covid-19 tún gbò̩nà è̩bùrú yo̩ sí Naijiria, ènìyàn márùndínnígba (195) lóòjó̩
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 29, 2020

Covid-19 tún gbò̩nà è̩bùrú yo̩ sí Naijiria, ènìyàn márùndínnígba (195) lóòjó̩

Covid-19 tún gbò̩nà è̩bùrú yo̩ sí Naijiria, ènìyàn márùndínnígba (195) lóòjó̩
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Awon to n se kokari ajakale arun to n da gbogbo agbaaye laamu (coronavirus), NDDC (National centre for disease control) gbe esi ayewo awon to ko arun jade lanaa.
Eyi ni o tun tii po ju lati ipari osu keji to ti wo orileede yii. Eyi seru ba opo eniyan sugbon awon onimo ilera ni ko sewu. Won ni arun naa ko ni pe kase nile nitiri pe ti “egun ba ti de ori hun, o fe yo niyen”.
Ninu marundinnigba (195) to sese yoju, ogorin lo wa lati ipinle Eko, mejidinlogoji(38) lati Kano,meedogun (15) lati Ogun, meedogun (15) lati Bauchi, mokanla (11) ni Bornu, mewaa (10) ni Gombe, mesan-an (9) ni Sokoto, marun-un (5) ni Edo ati Jigawa, meji(2) ni Zamfara nigba ti eyokookan (1) wa ni Rivers, Enugu, Delta, Abuja ati Nasarawa.
Apapo eniyan to koo ti wo eedegbejo-le-mejilelogbon (1532). Eniyan otalelugba-din marun-un (255) lo ti gba idande ti ori ko yo, nigba ti orileede yii padanu eniyan merinlelogoji (44)
Ki Eledua ba wa dawo aburu duro.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…