Ọ̀gá àgbà UCH ní kò sí ibùdó àyẹwò àrùn Coronavirus ní UCH
Ọ̀gá àgbà UCH ní kò sí ibùdó àyẹwò àrùn Coronavirus ní UCH
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀ga àgbà fún ilé ìwòsàn UCH, Ọ̀jọ̀gbọ́n Jesse Abiodun Otegbayo lọ sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gbàlejò Kọmísánà fétò ìlera nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Dókítà Bashir Bello nílé ìwòsàn náà.
Àtẹjáde kan tí ilé ìwòsàn UCH wá fi síta lẹ́yìn àbẹ̀wò náà ní lóòótọ́ nilé ìwòsàn náà ń tọ́jú afurasí alárùn Covid-19 kan lọ́wọ́ àmọ́, wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fi àyẹ̀wò rẹ ránṣẹ́ sí ikọ̀ ìjọba tó ń ṣe àyẹ̀wò árùn Coronavirus ni.
Àtẹ̀jáde náà fikùn pé, ilé ìwòsàn UCH sì ń dúró de èsì àyẹ̀wò náà láti ibùdó àyẹ̀wò níta, táwọn yóò si máa fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó aráyé létí bó bá ṣe ń lọ.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…