Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pàṣẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ láti ìpele kẹtàlá padà sí ẹnu iṣẹ́ lọ́jọ́ ajé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 26, 2020

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pàṣẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ láti ìpele kẹtàlá padà sí ẹnu iṣẹ́ lọ́jọ́ ajé

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pàṣẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ láti ìpele kẹtàlá padà sí ẹnu iṣẹ́ lọ́jọ́ ajé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ọgbọ́n kò ní í tán nínú àgbà kó má tún míì dá, ló mú kí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣèyí Mákindé pàṣẹ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti ìpele kẹtàlá sókè ó padà ṣẹ́nu iṣẹ́ láti ọjọ́ ajé tó ń bọ̀, pàápàá jùlọ àwọn to bá dá ọ́fíísì ní.

Gómìnà fi ọ̀rọ̀ yìí léde lóri àtẹjíṣẹ́ twitter rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìjíròrò pẹ̀lú ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lóri Corornavirus ní àwọn fẹnukò lórí ìgbésẹ̀ yìí pẹlú àwọn àlàálẹ̀.

Ṣèyí Mákindé ní gbogbo ẹni tí yóò bá padà sẹ́nu iṣẹ́ gbọdọ̀ máa gba ẹnu ọ̀nà kan ṣoṣo, tí wọ́n ó ṣí sílẹ̀ láti wọ sẹkitéríàtì nígbà tí gbogbo ìloro tó kù yóò wà ní títì pa, èyí ni lá’ti dẹ́kun ìtànkalẹ̀ àrùn apinni léèmí Corornavirus

Gbogbo ìpàdé yóò maa wáye lóri ayélujára bakan náà ni ko ni sí ààye fún àlejò láti wọlé àfi ti o ba pọ́n dandan.

Ó ní ìjọba yóò ṣètò àwọn ibùdó ti àwọn ènìyàn yóò ti máa fọ ọwọ́ wọ́n nínú ọgbà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan yóò máa gba “hand sanitizer” àti ìbòjú-bomú.

Gbogbo ilé oúnjẹ láyíká, ilé iṣẹ́ ìjọba yóò sì wà ni títì pa, nítorí náà ki àwọn òṣìṣẹ́ máa gbé oúnjẹ wá láti ilé.

Gómìnà fi kún un pé àwọn yóò dẹ ọwọ́ òfin kóníléógbélé díẹ̀ ti àwọ̀n ènìyàn yóò maa jáde láàrin ààgo méje alẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí kí àwọn àgbẹ le máa ri iṣẹ́ wọ́n ṣe.

Mákindé ní àwọn nǹkan ìrànwọ́ tí ìjọba pèsè fún ará ìlú ti wà ní ṣẹpẹ́ báyìí tí wọ́n sì ti yan ìdílé ẹgbẹ̀run ‘lọ́nà ààdọ́rùn sọ́tọ̀ láti jẹ àǹfàní ètò náà

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…