Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ajínigbé tí palẹ̀mọ́ àwọn ìbejì Ààfáà àgbà oníwáàsí Sheikh Taofeeq Akeugbagold
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 26, 2020

Àwọn ajínigbé tí palẹ̀mọ́ àwọn ìbejì Ààfáà àgbà oníwáàsí Sheikh Taofeeq Akeugbagold

Àwọn ajínigbé tí palẹ̀mọ́ àwọn ìbejì Ààfáà àgbà oníwáàsí Sheikh Taofeeq Akeugbagold

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá kan tí ẹnikẹ́ni ò lè sàpèjúwe wọn tí palẹ̀ àwọn ìbejì Ààfáà àgbà oníwáàsí n nì Sheikh Taofeeq Akeugbagold mọ́ ó. Ààfáà àgbà náà ló fí ọ̀rọ̀ yìí léde lójú òpó abánidọ́rẹ̀ẹ́ síwèé wojú( Facebook) . Pé ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì náà wáyé ní nǹkan bí aago mẹ́jọ àṣálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta tí òǹkà ààwẹ̀ di méjì. Ó tẹ̀síwájú pé nǹkan bíi Ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí òun tí rékọjá sí ibi tí òun ó ti sètò wáàsí ni àjálù náà wáyé.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tí fi ọ̀rọ̀ náà tó ilé iṣẹ ọlọ́pàá létí, síbẹ̀, ó ní àánú ló ń bèèrè fún . Kí gbogbo ìlú o máa gbàdúrà fún òun kí àwọn tó ṣiṣẹ́ náà síjú àánú wo òun , kí wọ́n yááfi òun fún Ọlọ́run nínú oṣù tí a wà yìí.
Ó ní kí wọ́n wò tí ìyá àwọn ọmọ òun náà tó ṣé pé ipò àgàn ló wà fún odidi ọdún méjìlá kí àánú Ọlọ́run tó ṣokùnfà bí a ṣé rí ọmọ bí.
Ní báyìí, ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, nígbà tí ó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀. Alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ náà
Ọ̀gbẹ́ni Olugbenga Fadeyi ṣọ pé ọwọ́ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tí tẹ àwọn afurasí kàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wọn yóó sèrànwọ́ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá nítẹsiwaju ìwádìí wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…