Home ÀKỌ̀TUN Gbogbo ìrẹsì tí Ìjọba fúnwa ló ti bàjẹ́, nítorí náà la se kọ̀ ọ́– Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 25, 2020

Gbogbo ìrẹsì tí Ìjọba fúnwa ló ti bàjẹ́, nítorí náà la se kọ̀ ọ́– Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Gbogbo ìrẹsì tí Ìjọba fúnwa ló ti bàjẹ́, nítorí náà la se kọ̀ ọ́– Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní oúńjẹ ìwọ̀sí, tiketike là á kọ̀ ọ́.(Ẹ ẹ foríjìn mí,ẹnu ùn mi àgòyà).

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kọ ẹgbẹ̀sán ìrẹsì tó jẹ́ ìrànwọ́ tí Ìjọba àpapọ̀ fi ránṣẹ́ sí wọn o.
Àwọn alámòjútó ètò oúnjẹ nípìńlẹ̀ Oyo tí fi léde fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,pe kòkòrò wà nínú ìrẹsì náà, tí Ìjọba àpapọ̀ fi ránṣẹ bíi ohun ìtùnú láti ọdọ ìjọba àpapọ̀.

Ṣùgbọ́n tí àfihàn rẹ̀ fojú hàn gbangba pé àwọn oúnjẹ náà ti bàjẹ́ lọ́wọ́ kòkòrò.

Wọ́n ní yóó sòro láti pín irúfẹ́ ìrẹsì yìí fún àwọn ará ìlú lásìkò yìí tí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí gbòde kankan.

Àwọn ìgbìmọ̀ tó ń ṣamójútó pínpín oúnjẹ ní ìpínlẹ̀ náà ṣọ pé, ìbí tí àwọn to kò oúnjẹ náà fún àwọn sewọ́n lọ́jọ́
pamọ́ sí dáa, ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé, kòkòrò ti ba ọpọ ìrẹsì náà jẹ́ mọ́ inú àwọn àpò ìrẹsì tí wọ́n sewọ́n lọ́jọ́ sí.

Wọ́n kádíì ọ̀rọ̀ wọn pé, àwọn ríigbà, ṣùgbọ́n àwọn ò lè fí síta fún àwọn èèyàn , yóó jẹ́ Ìdùnnù àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bí ìjọba àpapọ̀ bá le fún àwọn ní òmiiran ní ìpàrọ̀ dípò o àwọn tí kòkòrò ti bàjẹ́ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…