Èèyàn 1096 ló ti ni àrùn Coronavirus ní Nàíjírìa báyìí
Èèyàn 1096 ló ti ni àrùn Coronavirus ní Nàíjírìa báyìí
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ àrùn apinni léèmí Covid 19 ti wá di kàkà kó sàn lára ìyá àjẹ́, lórílẹ̀ yìí o, tó ń fi gbogbo ọmọ rẹ bí obìnrin jọ, bí òǹkà tí n peléke sí i lójúmọ́ lójúmọ́.
Ni báyìí, èèyàn mẹ́rìnléláàdọ́fà míràn ni àyẹ̀wò tún ti fihàn pé ó ní àrùn apinni léèmí Coronavirus báyìí lórílẹ̀-èdè Naijiria.
Àtẹ̀jáde kan tí àjọ tó ń rí sí ìgbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NCDC fi síta lójú òpó twitter rẹ ṣàlàyé pé, ọgọ́rin nínú àwọn èèyàn náà wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, àti mọ́kànlélógún wá láti ìlú Gombe.
Bákan náà ló ní àwọn márùn ún wá láti ìlú Àbújá, méjì ní Zamfara àti Edo pẹ̀lú ẹyọ ọ̀kan ní Ògùn, Ọ̀yọ́, Kàdúná àti Sókótó.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…