Home ÀKỌ̀TUN Ìwádìí bẹrẹ lórí bí èèyàn 100, 000 ṣe kópa níbi ètò ìsìnkú Ìmáàmù ní Bangladesh
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 24, 2020

Ìwádìí bẹrẹ lórí bí èèyàn 100, 000 ṣe kópa níbi ètò ìsìnkú Ìmáàmù ní Bangladesh

Ìwádìí bẹrẹ lórí bí èèyàn 100, 000 ṣe kópa níbi ètò ìsìnkú Ìmáàmù ní Bangladesh

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba orílẹ̀-èdè Bangladesh ti gbé Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta kan kalẹ̀ láti se ìwádìí ohun tó mú kí èèyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà Ọgọ́rùn tàpá sí òfin kónílé-ó-gbélé tí Ìjọba fi lélẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀.

Wọ́n tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin nígbà tí wọ́n kópa nínú ìsìnkú Maulana Jubayer Ahmed Ansari tó jẹ́ aṣíwájú kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tó rọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Islam nílẹ̀ náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ti sọ àwọn èèyàn sínú ipòríru ọkàn pé ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kó àrùn apinni léèmí Covid 19 nítorí rẹ̀.

Orile-ede Bangladesh ti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé èèyàn ẹgbẹ̀rún méjì lé nírinwó ló ti kó àrùn yí tí èèyàn
mọ́kànléláàdọ́rùn ṣì ti pàdánù emi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…