Home ÀKỌ̀TUN Ìpínlẹ Ogun tú ẹlẹwọn mọkàndínláàdọta ó lé ní igba sílẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 24, 2020

Ìpínlẹ Ogun tú ẹlẹwọn mọkàndínláàdọta ó lé ní igba sílẹ

Ìpínlẹ Ogun tú ẹlẹwọn mọkàndínláàdọta ó lé ní igba sílẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹlẹ́wọ̀n mọkàndínláàdọta lé ní igba (249) gba òmìnira kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n márùn ún ní ìpínlẹ̀ Ògùn láti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Coronavirus.

Olóòtú ètò Ìdájọ́ ní Ìpínlẹ Ògùn, Adájọ́ Mosunmola Dipeolu ló fi èyí léde lásìkò tó ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.

Dipeolu ní àṣẹ ìjọba àpapọ̀ nipé kí wọ́n dín àwọn ènìyàn kú ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, kí ìtànkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Coronavirus má baà wọ ààrin wọn.

Ó pe àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ náà jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn olè jíjà, fífọ́lé onílé, ifiyajẹni ati awọn ẹsun kekeeke ti wọn fi kan wọn.

Bẹ́ẹ̀ ló pàrọwà sí àwọn ẹlẹ́wọ́n tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ náà láti rí pé wọn kò padà sí ìdí ìwà ìbàjẹ́ mọ́ àti wí pé wọ́n gbọdọ̀ wúlò fún ara wọn àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …