Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbé àgánráńdì sáwọn òpópónà tó wọ ìpínlẹ̀ náà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 24, 2020

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbé àgánráńdì sáwọn òpópónà tó wọ ìpínlẹ̀ náà

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun gbé àgánráńdì sáwọn òpópónà tó wọ ìpínlẹ̀ náà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gẹ́gẹ́ bí ara Ìlàkàkà rẹ̀ láti ríi dájú pé àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún àṣẹ kónílé-ó-gbélé rẹ̀ láti dènà àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí COVID-19, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọṣun ti gbé àgánrándì sí gbogbo àwọn òpópónà tó wọ ìpínlẹ̀ náà.

Èyí ń wáyé lẹ́yìn ìkéde tí Ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣe pé àṣẹ kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ́ mẹ́rìnlà tí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà pa kìí ṣe láago mélòó kan sí ago mélòó kan o, bí kò ṣe ọlọ́jọ́yípo eléyìí tí kò fi ààyè sílẹ̀ fún ìgbòkègbodò ọkọ tàbí ènìyàn bí ó ti wù kó mọ.

Kọmíṣọ́nnà fétò Ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Ọṣun, Arábìnrin Funkẹ aya Egbemode ṣàlàyé àwọn àgánrándì náà yóó sèrànwọ́ àti pinwọ bí àwọn ọkọ̀ ṣe ń wọ ìpínlẹ̀ náà lábẹ́ àṣẹ kónílé-ó-gbélé tí Ìjọba gbé kalẹ̀.

Ó ní Ìjọba ń sapá láti ríi pé ọwọ́jà àrùn apinni léèmí Coronavirus náà kò lọ sókè ju bó ṣe wà lọ́wọ́ yìí lọ ní ìpínlẹ̀ Ọṣun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…