Home ÀKỌ̀TUN Inú mi dùn láti sọ pé mo ti bọ́ lọ́wọ́ àrùn apinni léèmí Covid 19, lẹ́yìn tí mo gbàtọ́jú ọ̀sẹ̀ mẹ́rin- Nasir El-Rufai.
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 23, 2020

Inú mi dùn láti sọ pé mo ti bọ́ lọ́wọ́ àrùn apinni léèmí Covid 19, lẹ́yìn tí mo gbàtọ́jú ọ̀sẹ̀ mẹ́rin- Nasir El-Rufai.

Inú mi dùn láti sọ pé mo ti bọ́ lọ́wọ́ àrùn apinni léèmí Covid 19, lẹ́yìn tí mo gbàtọ́jú ọ̀sẹ̀ mẹ́rin- Nasir El-Rufai.

Fẹ́mi Akínṣọlá

El-Rufai ní ara òun ti dá ṣáká lẹ́yìn tó gbàtójú ọ̀sẹ̀ mẹ́rin lórí covid-19

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́rin tí mo fi gba ìtọ́jú lẹ́yìn tí mo lùgbàdì àrùn apinni léèmí coronavirus, inú mi dùn láti sọ pé ara à mi ti dá ṣáká báyìí.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai ló fọ̀rọ̀ náà léde lójú òpó Twitter L’ọ́jọ́rù.

El-Rufai ní ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àyẹ̀wò fihàn pé òun kò ní àrùn apinni léèmí Covid 19 mọ́.

”Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ àti àánú Rẹ̀,” El-Rufai ló sọ bẹ́ẹ̀, bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún àdúrà wọn lẹ́yìn tó kó àrùn apinni léèmí covid-19.

Ó ní kò rọrùn fún ẹbí òun nítorí ìbẹ̀rù mú wọn pé ó ṣeéṣe kí àrùn náà mú òun lọ, àti pé àwọn gán án lè tara òun kó àrùn náà.

El-Rufai tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣègùn ètò ìlera fún iṣẹ́ takun takun tí wọ́n ń ṣe, paàpá jùlọ lórí òun nígbà tí òun kó àrùn apinni léèmí náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…